Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 5, 2019
PHILIPPINES

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣọsẹ́ Ní Orílẹ̀-Èdè Philippines

Ìmìtìtì Ilẹ̀ Ṣọsẹ́ Ní Orílẹ̀-Èdè Philippines

Ní July 27, 2019, ìmìtìtì ilẹ̀ méjì tó jà ba ọ̀pọ̀ nǹkan jẹ́ ní erékùṣù kékeré Itbayat tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́rùn-ún méje ó dín mẹ́wàá (690) kìlómità sí Manila, lórílẹ̀ èdè Philippines. Ìmìtìtì ilẹ̀ yìí kọjá kékeré, èèyàn mẹ́sàn-án ló kú, ò ṣe èèyàn mérìnlélọ́gọ́ta (64) léṣe, ó sì ba ilé ọgọ́rùn-ún méjì àti mẹ́rìndínláàádọ́rin (266) jẹ́. Àwọn aláṣẹ ròyìn pé, ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ó dín méjìlélọ́gbọ̀n (2,968) èèyàn ló fara gbá nínú ìmìtìtì ilẹ̀ náà.

Kò sí ìkankan lára àwọn ará wa tó kú nínú ìmìtìtì ilẹ̀ yìí. Àmọ́ arábìnrin kan fara pa díẹ̀. Bákan náà, àwọn arákùnrin wa méjì ni ilé wọn bàjẹ́ gan-an.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì gbé Ìgbìmọ̀ Tó Ń Ṣètò Ìrànwọ́ Nígbà Àjálù dìde, àwọn ló sì ń bójú tó rírà àti pínpín àwọn ohun kòséémàní bí i oúnjẹ àti omi. Àwọn aṣojú ẹ̀ka ọ́fíìsì máa ṣèbẹ̀wò sí àwọn arákùnrin àti arábìnrin tí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí kan láti fi ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tù wọ́n nínú àti láti pèsè ohun tí wọn nílò fún wọn.

Gbogbo ìgbà là ń gbàdúrà fún àwọn arákùnrin àti arábìnrin wa tó fara gbá nínú àwọn ìmìtìtì ilẹ̀ tó ṣẹlẹ̀ láìpẹ́ yìí. A mọ̀ pé Jèhófà, “Ọlọ́run ìtùnú gbogbo,” á máa báa lọ láti bójú tó àìní àwọn ará wa.​—2 Kọ́ríńtì 1:3.