Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Bí nǹkan ṣe rí lẹ́yìn ilẹ̀ ríri tó ṣọṣẹ́ ní Natonin, lágbègbè Mountain Province

AUGUST 14, 2019
PHILIPPINES

Òjò Alátẹ́gùn Rọ́ Lu Orílẹ̀-Èdè Philippines

Òjò Alátẹ́gùn Rọ́ Lu Orílẹ̀-Èdè Philippines

Ní ìbẹ̀rẹ̀ August 2019, òjò alátẹ́gùn bẹ̀rẹ̀ lórílẹ̀-èdè Philippines pẹ̀lú òjò rẹpẹtẹ àti ìjì líle, èyí sì fa àkúnya omi àti ilẹ̀ ríri. Ó bani nínú jẹ́ pé ilẹ̀ tó rì náà pa arákùnrin kan tó ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀ nílùú Natonin, lágbègbè Mountain Province. Arákùnrin míì tí òun náà ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú-ọ̀nà àkànṣe onígbà díẹ̀ fara pa díẹ̀ nínú ilẹ̀ ríri kan náà. Nínú ìṣẹ̀lẹ̀ míì, àwókù pàǹtírí ṣe ọmọkùnrin ọlọ́dún mẹ́wàá kan léṣe, àmọ́ ó rí ìtọ́jú tó yẹ gbà.

Kò sí ilé àwọn arákùnrin wa tò bàjẹ́ jù. Àmọ́, ìjì líle tó ṣọṣẹ́ ní Negros Occidental ba Gbọ̀ngàn Ìjọba kan jẹ́, ó sì ya lára òrùlé ilé náà lulẹ̀.

Ẹ̀ka ọ́fíìsì Philippines àti alábòójútó àyíká ń pèsè ìtùnú fún àwọn ìdílé tí ìṣẹ̀lẹ̀ náà kàn, wọ́n sì ń fi Bíbélì tù wọ́n nínú.

Ó bani nínú jẹ́ láti gbọ́ nípa àdánù ńlá yìí, à sì ń gbàdúrà fún àwọn tó ń ṣọ̀fọ̀ ikú arákùnrin wa. À ń retí ọjọ́ iwájú kan nígbà tí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú “ò ní wá sí ìrántí.”​—Àìsáyà 65:17.