Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 2, 2019
RÙWÁŃDÀ

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àpéjọ Àgbègbè Lédè Adití Fún Ìgbà Àkọ́kọ́ Ní Rùwáńdà

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣe Àpéjọ Àgbègbè Lédè Adití Fún Ìgbà Àkọ́kọ́ Ní Rùwáńdà

Ní August 16 sí 18, 2019, àwọn arákùnrin wa ṣe àpéjọ agbègbè lédè adití ti Rùwáńdà nílùú Kigali, lórílẹ̀-èdè Rùwáńdà. Ìgbà àkọ́kọ́ tírú ẹ̀ máa wáyé rèé. Ọgọ́rùn-ún mẹ́fà àti ogún (620) èèyàn ló wà sí àpéjọ náà, àwọn adití mẹ́jọ ló sì ṣèrìbọmi.

Àwọn tó wá sí àpéjọ náà ń fi èdè adití kọ orin Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn àlejò láti iléeṣẹ́ ìjọba méjì ló wà ní àpéjọ yìí lọ́jọ́ Sunday, àwọn ni: Ọ̀gbẹ́ni Jean Damascène Bizimana tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùdarí Ẹgbẹ́ Àwọn Adití Ilẹ̀ Rùwáńdà àti Ọ̀gbẹ́ni Emmanuel Ndayisaba tó jẹ́ akọ̀wé àgbà fún Àjọ Tó Ń Bójú Tó Àwọn Aláàbọ̀ Ara lórílẹ̀-èdè Rwanda. Yàtọ̀ síyẹn, iléeṣẹ́ ìwé ìròyìn tó ń jẹ́ Ukwezi náà wà níbẹ̀ lọ́jọ́ Sunday, wọ́n sì gbé ìròyìn tó wúni lórí jáde lórí ìkànnì wọn.

Arábìnrin kan ń túmọ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ náà fún ẹnì kan tó fọ́jú tó sì tún yadi. Ó ń fi ọwọ́ ṣe àmì ohun tí wọ́n sọ sí i lọ́wọ́

Ọ̀gbẹ́ni Bizimana sọ pé: “Àpéjọ yìí ti dáa jù! Ẹ wo bí àwọn adití láti onírúurú agbègbè lórílẹ̀-èdè yìí ṣé jọ wà papọ̀. Ẹ ṣeun. A dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún bí wọ́n ṣe ń ti èdè àwọn adití lẹ́yìn. Ó yẹ káwọn aláṣẹ ìjọba wa wo irú àpéjọ tó ń fi bí àwọn èèyàn ṣe wà níṣọ̀kan báyìí hàn, kí wọn sì ṣe irú rẹ̀.”

Lọ́dún méjì sẹ́yìn, àwọn ohun mánigbàgbé méjì kan tún wáyé láàárín àwọn tó ń sọ èdè adití tí Rùwáńdà. Ní September 2017, ẹ̀ka ọ́fíìsì Rùwáńdà ṣe ilé-ẹ̀kọ́ àwọn aṣáájú-ọ̀nà lédè adití ti Rùwáńdà fún ìgbà àkọ́kọ́. Nígbà tó tún di September 2018, ẹ̀ka ọ́fíìsì bẹ̀rẹ̀ sí tú àwọn ìtẹ̀jáde wa sí èdè adití ti Rùwáńdà.

Arákùnrin Jean d’Amour Habiyaremye, tó jẹ́ aṣojú tí ẹ̀ka ọ́fíìsì rán wá sí àpéjọ àwọn adití yìí sọ pé: “A láyọ̀ láti rí ìtẹ̀síwájú tó ń bá iṣẹ́ ìwàásù láàárín àwọn tó ń sọ́ èdè adití ti Rùwáńdà, títí kan àpéjọ agbègbè yìí. Àkòrí àpéjọ náà ni ‘Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé!,’ a sì rí i pé lóòótọ́ ni àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìfẹ́ yìí hàn sí gbogbo èèyàn títí kan àwọn adití.”

Bí iṣẹ́ ìwàásù ṣe ń tẹ̀síwájú láàárín àwọn tó ń sọ èdè adití jẹ́ ẹ̀rí tó ṣe kedere pé Jèhófà ń bù kún wa!​—Sáàmù 67:1.