Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

SEPTEMBER 16, 2019
SOUTH AFRICA

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní Ìlú Johannesburg, Lórílẹ̀-Èdè South Africa

Àpéjọ Àgbáyé “Ìfẹ́ Kì Í Yẹ̀ Láé”! Ti Ọdún 2019 Tí A Ṣe Ní Ìlú Johannesburg, Lórílẹ̀-Èdè South Africa
  • Déètì: September 6 sí 8, 2019

  • Ibi Tí A Ti Ṣe É: Gbọ̀ngàn Ìwòran FNB ní ìlú Johannesburg, South Africa

  • Èdè: Gẹ̀ẹ́sì, Sesotho, Zulu

  • Àwọn Tó Wá: 58, 149

  • Àwọn Tó Ṣèrìbọmi: 476

  • Àwọn Tó Wá Láti Ilẹ̀ Òkèèrè: 6,000

  • Àwọn Ẹ̀ka Ọ́fíìsì Tá A Pè: Bòlífíà, ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Central Europe, Kóńgò (Kinshasha) Finland, Hong Kong, Hungary, Ísírẹ́lì, Japan, Kẹ́ńyà, Kòríà, Làìbéríà, Madagásíkà, Màláwì, Paraguay, Peru, Uganda, Amẹ́ríkà, Sáńbíà, Sìǹbábúwè.

  • Ìrírí: Àwọn aláṣẹ ọgbà ẹranko tó ń jẹ́ Lion and Safari Park, tó jẹ́ ọ̀kan lára ibi tí wọ́n ṣètò fún àwọn àlejò láti gbafẹ́ lọ, ṣàlàyé pé àwọn ò tíì rí i rí kí ọ̀pọ̀ èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ àti èdè wọn yàtọ̀ síra bẹ́ẹ̀ máa bọ́ sílẹ̀ látinú ọkọ̀ kan náà tó sì jẹ́ pé wọ́n ò bá ara wọn jiyàn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ò sì bá ara wọn jà. Orí àwọn aláṣẹ náà wú gan-an nígbà tí wọ́n rí i bí àwọn àlejò yẹn ṣe tẹ̀ lé ìtọ́ni tí wọ́n sì fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú àwọn òṣìṣẹ́ wọn, wọ́n sọ pé: “Inú wá dùn pé wọ́n wá.”

 

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń kí àwọn àlejò káàbọ̀ sí orílẹ̀-èdè South Africa ní pápákọ̀ òfuurufú

Àwọn arábìnrin mẹ́rin, ìyẹn àwọn ará ìlú méjì àtàwọn àlejò méjì ń pín ìwé ìkésíni láti fi pe àwọn èèyàn sí àpéjọ náà nígbà tí wọ́n wà lóde ẹ̀rí

Àwọn tó wá sí àpéjọ àgbègbè ń fi aṣọ ìbílẹ̀ wọn ya fọ́tò

Àwọn arákùnrin àti arábìnrin ń rẹ́rìn-ín bí wọ́n ṣe ń pàtẹ́wọ́ nígbà tí àpèjọ náà ń lọ lọ́wọ́

Ọ̀kan lára àwọn ọgọ́rùn-ún mẹ́rin àti mẹ́rìndínlọ́gọ́rin (476) tó ṣèrìbọmi

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí ń kí àwọn arákùnrin àti arábìnrin nígbà ìsinmi ọ̀sán

Ní ọjọ́ tó kẹ́yìn àpéjọ náà, wọ́n fi àwọn tó ń ṣe àkànṣe iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún tó wá láti òkèèrè han àwọn ará

Àwọn arábìnrin mẹ́ta ń ya fọ́tò lẹ́yìn tí àpéjọ náà parí

Nígbà ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó wáyé nírọ̀lẹ́, àwọn ará wa tó wọ aṣọ aláràbarà ilẹ̀ Áfíríkà ń fi orin dá àwọn ará wa lára yá