Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

OCTOBER 29, 2019
AZERBAIJAN

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Márùn-ún Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Gbà Wọ́n Láàyè Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Láre Ní Azerbaijan

Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ilẹ̀ Yúróòpù Dá Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Márùn-ún Tí Ẹ̀rí Ọkàn Wọn Kò Gbà Wọ́n Láàyè Láti Ṣiṣẹ́ Ológun Láre Ní Azerbaijan

Ní October 17, 2019, Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù dájọ́ pé kò yẹ kí wọ́n máa fìyà ọ̀daràn jẹ àwọn arákùnrin wa tí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọ́n láàyè láti ṣiṣẹ́ ológun ní Azerbaijan. Ìdájọ́ yìí fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé tí wọ́n bá fìyà jẹ ẹnì kan nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ ò gbà á láàyè láti ṣiṣẹ́ ológun, ṣe ni wọ́n ń fi ẹ̀tọ́ ẹni náà dù ú. Ìyẹn ẹ̀tọ́ láti ṣe ohun tó bá ẹ̀rí ọkàn ẹni mu, ẹ̀tọ́ láti ro ohunkóhun téèyàn bá fẹ́ àti ẹ̀tọ́ láti ṣe ẹ̀sìn tó bá wuni. Èyí ni ìgbà àkọ́kọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn Ti Ilẹ̀ Yúróòpù máa dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà láre ní orílẹ̀-èdè Azerbaijan.

Ìdájọ́ yìí wà fún ẹjọ́ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tá a ti kọ̀wé nípa ẹ̀ sí Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn láàárín ọdún 2008 sí 2015. Àwọn arákùnrin wa márùn-ún ni ẹjọ́ náà kàn: Mushfig Mammadov, Samir Huseynov, Farid Mammadov, Fakhraddin Mirzayev àti Kamran Mirzayev. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ni àwọn aláṣẹ sọ pé wọ́n jẹ̀bi tí wọ́n sì rán wọn lọ sẹ́wọ̀n ní Azerbaijan nítorí wọ́n kọ̀ láti ṣiṣẹ́ ológun. Ilé Ẹjọ́ Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn sọ pé níwọ̀n bó ti jẹ́ pé nítorí “ohun tí wọ́n fi tọkàntọkàn gbà gbọ́” ló mú kí àwọn arákùnrin wa kọ̀ láti wọṣẹ́ ológun, bí ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan ṣe dá wọ́n lẹ́bi lórí ọ̀rọ̀ yìí ta ko ohun tó wà nínú Àdéhùn Àjọṣe Ti Ilẹ̀ Yúróòpù Lórí Ẹ̀tọ́ Ọmọnìyàn. Ilé ẹjọ́ yìí tún sọ pé kó yẹ kó jẹ́ kìkì àwọn olórí ẹ̀sìn àti àwọn ọmọ ilé-ẹ̀kọ́ ìsìn tó lórúkọ nìkan ni wọ́n á máa gbà láyè láti ṣe iṣẹ́ míì dípò iṣẹ́ ológun. Ilé ẹjọ́ náà tún pa á láṣẹ fún ìjọba orílẹ̀-èdè Azerbaijan pé kí wọ́n san owó gbà-má-bínú fún àwọn arákùnrin wa yìí.

Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ṣé ṣàlàyé lákòókò ìgbẹ́jọ́ náà, nígbà tí orílẹ̀-èdè Azerbaijan dara pọ̀ mọ́ Ìgbìmọ̀ Ilẹ̀ Yúróòpù lọ́dún 2001, wọ́n gbà láti ṣe òfin pé kí iṣẹ́ míì wà téèyàn lè ṣe dípò iṣẹ́ ológun. Bákan náà, òfin orílẹ̀-èdè Azerbaijan fàyè gba pé kí ẹni tí ohun tó gbà gbọ́ bá ta ko pé kó ṣe iṣẹ́ ológun lọ ṣe iṣẹ́ àṣesìnlú dípò iṣẹ́ ológun. Àmọ́, ṣe ni àwọn aláṣẹ ń fi ọ̀rọ̀ falẹ̀ láti ṣètò iṣẹ́ àṣesìnlú yìí, tí wọ́n sì ń báa lọ láti fìyà jẹ àwọn arákùnrin wa nítorí ẹ̀rí ọkàn wọn kò gbà wọn láyè láti ṣiṣẹ́ ológun.

A nírètí pé ìdájọ́ ilé ẹjọ́ yìí á sún àwọn aláṣẹ orílẹ̀-èdè Azerbaijan láti ṣètò àwọn iṣẹ́ míì dípò iṣẹ́ ológun. Ní báyìí ná, ṣe là ń gbàdúrà pé kí àwọn arákùnrin wa ní Azerbaijan máa báa lọ láti sin Jèhófà pẹ̀lú ìgboyà.​—Sáàmù 27:14.