Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Abúlé Apex rèé, ní ìlú Iqaluit tó wà ní erékùṣù Baffin, agbègbè Nunavut, lórílẹ̀-èdè Kánádà

APRIL 17, 2020
KÁNÁDÀ

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020​—Orílẹ̀-èdè Kánádà

Wọ́n Ṣe Ìrántí Ikú Kristi Ní Ìkángun Ilẹ̀ Ayé

Ìrántí Ikú Kristi Tá A Ṣé Lọ́dún 2020​—Orílẹ̀-èdè Kánádà

Ìjọ Iqaluit wà ní ọ̀kan lára àwọn erékùṣù tí yìnyín ti máa ń jábọ́ gan-an lápá àríwá orílẹ̀-èdè Kánádà. Àwọn akéde mẹ́tàdínlógún (27) ló wà nínú ìjọ yẹn, nínú àwọn ẹni márùndínlọ́gọ́ta (55) tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, méjìlá (12) ló dara pọ̀ mọ́ wọn lórí ẹ̀rọ ayélujára láti gbọ́ àsọyé Ìrántí Ikú Kristi, inú wọn sì dùn gan-an pé àwọn ṣe bẹ́ẹ̀.

Látilẹ̀, kò lè rọrùn rárá fún èyí tó pọ̀ lára àwọn tí wọ́n ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì láti wá sí Ìrántí Ikú Kristi, ó tiẹ̀ lè má ṣeé ṣe rárá ni. Ìdí sì ni pé ìpínlẹ̀ ìwàásù ìjọ náà tóbí gan-an, ó bẹ̀rẹ̀ láti ìlú Kimmirut lọ sí ìyànníyàn ìlú Grise Fiord tó jẹ́ apá ibi tó jìnnà jù lọ ní apá àríwá orílẹ̀-èdè Kánádà.

Alàgbà kan nínú ìjọ Iqaluit tó ń jẹ́ Isaac Demeester sọ pé: “Ọdún yìí ni ìgbà àkọ́kọ́ táwọn tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi. Ẹnì kan tá à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní agbègbè Grise Fiord pe àwọn mẹ́rin míì, bó ṣe di pé àwọn márùn-ún ló dara pọ̀ mọ́ wa láti ṣe Ìrántí Ikú Kristi, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà wọn jìn gan-an sí wa.”

Bí nǹkan ṣe rí lásìkò tí àrùn COVID-19 gbòde yìí mú kí ọ̀pọ̀ lára àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà ní ìjọ Iqaluit rí bó ti ṣe pàtàkì tó pé ká mọ onírúurú ọ̀nà tá tún lè gbà wàásù.

Arábìnrin Kathy Burechailo sọ pé: “À ń pe àwọn èèyàn tó wà láwọn agbègbè oníyìnyìn ní ìlà òòruń orílẹ̀-èdè yìí lórí fóònù, a sì ń báwọn sọ̀rọ̀. Inú mi dùn gan-an pé mo lè bá àwọn èèyàn tó wà làwọn ọ̀nà jíjìn yẹn sọ̀rọ̀ Jèhófà! Ìdí sì ni pé wọn ò lè jáde nílé, wọ́n nílò ẹni tó máa tù wọ́n nínú.”

Arábìnrin Laura McGregor sọ pé: “Nǹkan ò rọrùn rárá fún wa ní ìlú Iqaluit látìgbà tí oníkálùkù wa ti wà nílé nítorí àrùn tó gbòde yìí. Kò sówó lọ́wọ́, ẹ̀rù sì tún ń bà ọ̀pọ̀ èèyàn torí pé wọn ò mọ ohun tó lè ṣẹlẹ̀ bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́. Ìgbà àkọ́kọ́ rèé tá a màá ṣe búrẹ́dì Ìrántí Ikú Kristi ní ìdílé wa. Àmọ́ a gbádùn bá a ṣe jọ wà pa pọ̀. Ó jẹ́ ká túbọ̀ mọyì bí ètò Ìrántí Ikú Kristi ṣe rọrùn tó àti bí kò sì la ariwo lọ. A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé ohun tá a nílò wà lárọ̀ọ́wọ́tó, kò sì ṣòro ṣe.”

Arákùnrin Demeester fi kún un pé: “Òótọ́ ni pé àrùn COVID-19 yìí kò jẹ́ ká lè wà pa pọ̀ bá a ṣe máa ń ṣe látẹ̀yìn wá, síbẹ̀ ìyàlẹ́nu ló jẹ́ pé a túbọ̀ sún mọ́ra gan-an lásìkò Ìrántí Ikú Kristi yìí. Mánigbàgbé ni Ìrántí Ikú Kristi tọdún yìí jẹ́!”

Àwọn ará tó wà ní ìjọ Iqaluit nírètí pé àwọn náà máa ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tiwọn láìpẹ́, tí ipò nǹkan bá ti yí pa dà sí rere. Ní báyìí ná, ó dá wa lójú pé Jèhófà máa bù kún gbogbo ìsapá wọn láti rí i pé ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run dé àwọn ibi tó jìnnà jù lọ lápá àríwá orílẹ̀-èdè Kánádà, tó jẹ́ ọ̀kan lára ibi tó jìnnà jù lọ ní ayé!​—Ìṣe 1:8.