Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 29, 2020
MALAWI

Ìpàdé Ìjọ Lórílẹ̀-Èdè Màláwì Dé Ọ̀dọ̀ Ẹgbàágbèje Èèyàn Lórí Tẹlifíṣọ̀n àti Rédíò

Ìpàdé Ìjọ Lórílẹ̀-Èdè Màláwì Dé Ọ̀dọ̀ Ẹgbàágbèje Èèyàn Lórí Tẹlifíṣọ̀n àti Rédíò

Ìgbìmọ̀ Ẹ̀ka orílẹ̀-èdè Màláwì ti ṣètò láti gbé àwọn ìpàdé ìjọ wa sáfẹ́fẹ́ lórí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò lórílẹ̀-èdè náà. Àwọn ètò yìí délé dóko, kò mọ sọ́dọ̀ àwọn ará wa nìkan. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Màláwì lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún (100,000). Àwọn oníròyìn sì fojú bù ú pé lópin ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan, èèyàn tó tó mílíọ̀nù méjì ló ń wo ìpàdé orí tẹlifíṣọ̀n náà, tí mílíọ̀nù mẹ́jọ sì ń tẹ́tí sí rédíò.

Bọ́rọ̀ ṣe rí lọ́pọ̀ orílẹ̀-èdè, àwọn ará wa lórílẹ̀-èdè Màláwì náà ò le ṣèpàdé nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba, torí àrùn tó gbòde kan yìí. Ọ̀pọ̀ nínú àwọn akéde ìjọ ló ní tẹlifíṣọ̀n tàbí rédíò. Nípa bẹ́ẹ̀, ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò yìí máa wúlò fún àwọn tí kò lówó láti lo Íńtánẹ́ẹ̀tì, tí wọn ò sì lè ṣèpàdé ìjọ látorí ẹ̀rọ lọ́nà tí wọ́n á fi máa rí àwọn ará yòókù.

Èdè Chichewa tó jẹ́ èdè tí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn ń sọ lórílẹ̀-èdè náà la fi ń ṣe àwọn ìpàdé náà. Gbogbo ètò orí tẹlifíṣọ̀n náà la tún ń túmọ̀ sí Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Màláwì bó bá ṣe ń lọ lọ́wọ́. Láfikún sí àsọyé fún gbogbo èèyàn, nínú àwọn ìpàdé náà, a tún máa ń ṣàfihàn àwọn fídíò wa àti Bíbélì kíkà bí ẹni ṣe eré ìtàn. Lópin ìpàdé náà, a máa ń sọ fáwọn òǹwòran àtàwọn olùgbọ́ pé kí wọ́n lọ sórí ìkànnì jw.org tí wọ́n bá fẹ́ rí ìsọfúnni púpọ̀ sí i láwọn èdè míì.

Àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò yìí ti mú kí ohun táwọn kan ń rò nípa àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà yí pa dà. Ọkùnrin kan kọ̀wé pé: “Láti bíi ọ̀sẹ̀ mélòó kan ni mo ti ń gbọ́ ìwàásù yín lórí rédíò. Ó jẹ́ kí n rí àwọn òótọ́ ọ̀rọ̀ kan nípa irọ́ táwọn èèyàn máa ń pa mọ́ yín. Ìwàásù yín yàtọ̀ sí tàwọn ẹlẹ́sìn yòókù, ó wọ̀ wá lọ́kàn gan-an!” Ọkùnrin yẹn àti ìdílé rẹ̀ ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.

Augustine Semo, tó ń ṣe kòkáárí Ẹ̀ka Tó Ń Gbéròyìn Jáde ní Màláwì sọ pé: “Àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n àti rédíò yìí ti jẹ́ ohun èlò tó ṣe pàtàkì láti ran àwọn ará wa lọ́wọ́ kí wọ́n lè máa bá ìjọsìn Ọlọ́run lọ láìdáwọ́dúró. Ó tún ti jẹ́ kí àwọn tí kìí ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà mọ̀ nípa àwọn ẹ̀kọ́ wa tó dá lórí Bíbélì. Nígbà tí ipò nǹkan bá padà bọ̀ sípò ní Màláwì, a retí pé ọ̀pọ̀ ni yóò dara pọ̀ mọ́ wa làwọn ibi tá a ti ń ṣèpàdé.”

A láyọ̀ láti mọ̀ pé àwọn ará wa àti àwọn míì ní Màláwì láǹfààní láti máa sin Jèhófà lákòókò tó le koko yìí. Èyí jẹ́ ká túbọ̀ mọrírì ‘ẹrú olóòótọ́,’ tó ń rí i dájú pé gbogbo èèyàn láǹfààní láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Bíbélì.​—Mátíù 24:45.