Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Venezuela: Arábìnrin kan ń gbohùn sílẹ̀ ní èdè Warao (òkè lápá òsì), arákùnrin méjì tó wà lẹ́nu iṣẹ́ lára àwùjọ atúmọ̀ èdè Piaroa (ìsàlẹ̀ lápá òsì). South Korea: Ìdílé kan ń wo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè ọdún 2020 (lápá ọ̀tún)

SEPTEMBER 4, 2020
ÌRÒYÌN KÁRÍ AYÉ

Àpéjọ Agbègbè Ọdún 2020​—⁠Àwọn Atúmọ̀ Èdè Parí Iṣẹ́ Wọn Láìka Ọ̀pọ̀ Ìṣòro Sí

Àpéjọ Agbègbè Ọdún 2020​—⁠Àwọn Atúmọ̀ Èdè Parí Iṣẹ́ Wọn Láìka Ọ̀pọ̀ Ìṣòro Sí

Àpéjọ Agbègbè “Ẹ máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020 ló tíì ṣàrà ọ̀tọ̀ jù lọ nínú ìtàn àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti òde òní. Ó ju ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) èdè tí wọ́n túmọ̀ àpéjọ náà sí, àtilé làwọn èèyàn sì ti wò ó. Àwọn atúmọ̀ èdè gbọ́dọ̀ ṣiṣẹ́ wọn bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n dojú kọ ọ̀pọ̀ ìṣòro, wọn ò fi bẹ́ẹ̀ láwọn nǹkan tí wọ́n lẹ̀ fi ṣiṣẹ́, ìwọ̀nba àkókò ni wọ́n sì ní.

Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè Kikuyu lórílẹ̀-èdè Kenya sọ pé: “Torí pé kò sáyè àti wọlé tàbí jáde ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, àwọn ará díẹ̀ la ní tá a lè gba ohùn wọn sílẹ̀. Ká lè yanjú ìṣòro yìí, àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà láwọn agbègbè tó jìnnà sí wa la lò. Inú wa dùn gan-an pé a láǹfààní láti rí bí ẹ̀mí Jèhófà ṣe ń ṣiṣẹ́.”

Irú ìṣòro kan náà ni àwùjọ atúmọ̀ Èdè Adití Lọ́nà ti Kòríà àti àwùjọ atúmọ̀ èdè àwọn ará Kòríà ní. Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn atúmọ̀ èdè láti ilé ò lè wá sí Bẹ́tẹ́lì láti wá gbohùn sílẹ̀.

Wọ́n ṣètò ibi kan sílé arákùnrin kan kí wọ́n lè ṣe àwọn àsọyé àtàwọn fídíò Lédè Adití Lọ́nà ti Kòríà níbẹ̀

Láti yanjú ìṣòro yìí, ṣe làwọn ará ṣètò yàrá ìgbohùnsílẹ̀ nínú ilé wọn. Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé gbogbo ohun tá a nílò fún ìgbohùnsílẹ̀ làwọn ará fi ṣètìlẹ́yìn. Yàtọ̀ síyẹn, torí pé a ti wọ́gi lé gbogbo ìpàdé tá a máa ń ṣe láwọn àpéjọ wa, ó ṣeé ṣe fún ẹ̀ka ọ́fíìsì láti lo àwọn kámẹ́rà tó wà láwọn Gbọ̀ngàn Àpéjọ kí wọn le fi ká ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sílẹ̀ ní èdè àwọn adití.

Lórílẹ̀-èdè Venezuela, kò rọrùn fáwọn atúmọ̀ èdè kan láti ṣiṣẹ́ torí pé íńtánẹ́ẹ̀tì wọn ò ṣiṣẹ́ dáadáa. Àwọn míì ò ní àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n nílọ̀. Àmọ́, àwọn atúmọ̀ èdè tó láròjinlẹ̀ yìí lo ohun tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó láti ṣiṣẹ́ wọn. Bí àpẹẹrẹ, àwọn atúmọ̀ èdè láwọn agbègbè kan lo ibùsùn kí ariwo má bàa ṣèdíwọ́ nígbà tí wọ́n ń gbohùn sílẹ̀.

Ní Juba, lórílẹ̀-èdè South Sudan, àwọn ará mọ́kànlá ló ń túmọ̀ ìtẹ̀jáde sí èdè Zande. Ọ̀kan lára àwọn atúmọ̀ èdè náà sọ pé: “Nígbà tí mo gbọ́ pé a máa gbohùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè náà sílẹ̀, mo sọ pé, ‘Kò lè ṣeé ṣe! Kò sí bá a ṣe lè gbohùn gbogbo ìtòlẹ́sẹẹsẹ àpéjọ agbègbè tó ní fídíò àti àtẹ́tísí tó ju àádọ́rùn-ún (90) sílẹ̀ láàárín oṣù méjì.’ Ní báyìí tá a ti parí iṣẹ́ náà, ó ti wá dá mi lójú pé kò sóhun tó lè dí Jèhófà lọ́wọ́ láti ṣe ohun tó ní lọ́kàn. Ọ̀nà tó gbà ń ṣe nǹkan máa ń yani lẹ́nu gan-an!”​—⁠Mátíù 19:⁠26.

Ẹ̀bùn látọ̀dọ̀ Jèhófà ni ìtòlẹ́sẹẹsẹ Àpéjọ Agbègbè “Ẹ máa Yọ̀ Nígbà Gbogbo”! ti Ọdún 2020 jẹ́ lóòótọ́, “ẹni tó fẹ́ ká gba onírúurú èèyàn là, kí wọ́n sì ní ìmọ̀ tó péye nípa òtítọ́.”​—1 Tímótì 2:4.