Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

DECEMBER 31, 2021
THAILAND

Ó Ti Pé Ọdún Márùndínlọ́gọ́rin Tá A Ti Ń Tẹ Ilé Ìṣọ́ Lédè Thai

“Ẹ Ní Ìgbàgbọ́ Nínú Jèhófà Kẹ́ Ẹ sì Ṣiṣẹ́ Kára, Ó Dájú Pé Ẹ Máa Rí Atúmọ̀ Èdè”

Ó Ti Pé Ọdún Márùndínlọ́gọ́rin Tá A Ti Ń Tẹ Ilé Ìṣọ́ Lédè Thai

January 1, ọdún 2022 ló pé ọdún márùndínlọ́gọ́rin (75) tá a kọ́kọ́ tẹ Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Thai.

Ọdún 1931 la kọ́kọ́ wàásù ìhìn rere lórílẹ̀-èdè Thailand. Nígbà táwọn ará kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù lórílẹ̀-èdè Thailand, ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìtẹ̀jáde ni wọ́n fún àwọn èèyàn lédè Chinese, Gẹ̀ẹ́sì àti Japanese. Nígbà yẹn, ìwé pẹlẹbẹ Protection nìkan ló ṣì wà lédè Thai.

Àwọn aṣáájú-ọ̀nà mẹ́ta tó wá láti ilẹ̀ òkèèrè tó sì ń sìn lórílẹ̀-èdè náà rí i pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó lè dé ọkàn àwọn èèyàn, wọ́n nílò ọ̀pọ̀ ìtẹ̀jáde lédè Thai. Arákùnrin Willi Unglaube kọ̀wé sí Arákùnrin Rutherford pé kó ran àwọn lọ́wọ́. Arákùnrin Rutherford fèsì pé: “Ẹ ní ìgbàgbọ́ nínú Jéhófà kẹ́ ẹ sì ṣiṣẹ́ kára, ó dájú pé ẹ máa rí atúmọ̀ èdè.”

Ní December ọdún 1939, Arákùnrin Kurt Gruber àti Arákùnrin Willi Unglaube ń wàásù ní apá àríwá orílè-èdè Thailand. Ọ̀gá àgbà Ilé ìwé Àwọn Obìnrin ní ìlú Chiang Mai tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Chomchai Inthaphan rí ọ̀kan lára ìtẹ̀jáde táwọn ará wa pín lédè Gẹ̀ẹ́sì. Chomchai tó gbọ́ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti Thai dáadáa wá rí i pé òun ti rí òtítọ́.

Chomchai Inthaphan

Láìka àtakò tí Chomchai dojú kọ láti ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn àti owó tó jọ jú tí wọ́n fi lọ̀ ọ́ ní ilé ìwé tó ti ń ṣiṣẹ́, ó kọ̀wé fi ṣọ́ọ̀ṣì àti ilé ìwé náà sílẹ̀, ó sì di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìwé àkọ́kọ́ táwọn arákùnrin náà ní kó túmọ̀ ni ìwé Salvation. Nígbà tó yá, wọ́n pe Chomchai sí Bẹ́tẹ́lì nílùú Bangkok, ó sì di ọ̀kan lára àwọn tó kọ́kọ́ sìn níbẹ̀. Ọ̀pọ̀ ọdún ló fi jẹ́ pé òun nìkan ló ń túmọ̀ àwọn ìwé wa sí èdè Thai. Bọ́dún ṣe ń gorí ọdún, ọ̀pọ̀ àwọn obìnrin tó jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́, wọ́n sì kúnjú ìwọ̀n láti ṣiṣẹ́ atúmọ̀ èdè.

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, iṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè Thai dáwọ́ dúró, àmọ́ wọ́n pa dà bẹ̀rẹ̀ nígbà tógun náà parí. Wọ́n túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ January 1947 sí èdè Thai, wọ́n sì fi ẹ̀rọ mimeograph tẹ ọgọ́rùn-ún méjì (200) ìwé náà nílé àwọn míṣọ́nnárì. Bí wọ́n sì ṣe máa ń tẹ̀ ẹ́ nìyẹn lóṣooṣù. Àmọ́ nígbà tó di ọdún 1952, iye ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ ti tó ọgọ́rùn-ún márùn-ún (500) lóṣooṣù. Torí náà, àwọn ará bẹ̀rẹ̀ sí í lo ilé iṣẹ́ ìtẹ̀wé láti tẹ àwọn ìtẹ̀jáde náà. Ní September 1993, ẹ̀ka ọ́fíìsì Japan bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ Ilé Ìṣọ́ àti lédè Thai kó lè dọ́wọ́ àwọn èèyàn kárí ayé.

Àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka tó ń túmọ̀ èdè Thai àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Thai

Lónìí, nǹkan bí ọgọ́rin (80) àwọn ará lọ́kùnrin àti lóbìnrin ló ń ṣiṣẹ́ ìtúmọ̀ èdè ní ẹ̀ka ọ́fíìsì Thailand àti láwọn ọ́fíìsì àwọn atúmọ̀ èdè méjì. Yàtọ̀ sí èdè Thai, wọ́n tún máa ń túmọ̀ Ilé Ìṣọ́ sí èdè Akha, Lahu, Laotian, àti Èdè Àwọn Adití Lọ́nà ti Thai.

Nǹkan tó ju ẹgbẹ̀rún márùn-ún (5,000) àwọn akéde tó wà ní ìpínlẹ̀ tí ẹ̀ka ọ́fíìsì Thailand ń bójú tó ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà bí wọ́n ṣe tú Ilé Ìṣọ́ sí èdè wọn.​—Òwe 10:22.