JUNE 15, 2015
AZERBAIJAN
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ní Káwọn Aláṣẹ ní Azerbaijan Dá Àwọn tí Wọ́n Tì Mọ́lé Láìṣẹ̀ Sílẹ̀
Ní February 17, 2015, àwọn aláṣẹ lórílẹ̀-èdè Azerbaijan mú obìnrin méjì tí wọ́n jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì tì wọ́n mọ́lé torí pé wọ́n ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ fáwọn míì. Wọn ò tíì gbọ́ ẹjọ́ wọn, wọ́n ṣì wà látìmọ́lé, àwọn aláṣẹ sì ń fìyà jẹ wọ́n gan-an níbẹ̀, àfi bíi pé ọ̀daràn paraku ni wọ́n. Gbọ́ bí ẹnì kan tó jẹ́ aṣojú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílẹ̀ Yúróòpù ṣe ṣàlàyé ohun tójú àwọn obìnrin yìí ń rí.