ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ August 2013

Ẹ̀dà yìí sọ bá a ṣe lè jẹ́ mímọ́, bá a ṣe lè wúlò nínú iṣẹ́ Ọlọ́run, bá ò ṣe ní máa dá Ọlọ́run lẹ́bi nítorí ìṣòrò wa àti bá ṣe lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì.

A Ti Sọ Yín Di Mímọ́

Ṣàyẹ̀wò ohun mẹ́rin tó máa ràn wá lọ́wọ́ láti jẹ́ mímọ́ lójú Ọlọ́run ká sì túbọ̀ wúlò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ǹjẹ́ ó yẹ kí àwọn òbí máa jókòó ti ọmọ wọn tá a yọ lẹ́gbẹ́ láwọn ìpàdé ìjọ?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà ‘Ń Bá Mi Gbé Ẹrù Mi Lójoojúmọ́’

Kí ló mú kí arábìnrin kan ní Nàmíbíà máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fún ohun tó ti lé lógún ọdún, bó tiẹ̀ jẹ́ pé onírúurú àìlera ló ń bá a fínra?

Má Ṣe “Kún Fún Ìhónú Sí Jèhófà”

Àwọn kan ń bá Ọlọ́run bínú. Wọ́n ń dá a lẹ́bi pé òun ló fà ìṣòro wọn. Báwo la ṣe lè yẹra fún ìdẹkùn yìí?

Ẹ̀yin Òbí, Ẹ Kọ́ Ọmọ Yín Láti Kékeré

Ìgbà wo gan-an ló yẹ kí àwọn òbí bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn ọmọ wọn? Kí ló yẹ káwọn òbí fi kọ́ ọmọ?

Ẹ Máa Gba Ti Ara Yín Rò Kẹ́ Ẹ Sì Máa Fún Ara Yín Ní Ìṣírí

Báwo la ṣe lè ran ara wa lọ́wọ́ láti máa fi ìṣòtítọ́ sin Ọlọ́run lákòókò ìṣòro?

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

Sátánì kò fẹ́ ká rí ojúure Ọlọ́run. Kí la lè ṣe tí àárín àwa àti Jèhófà kò fi ní bà jẹ́?

Máa Ronú Nípa Irú Èèyàn Tó Yẹ Kó O Jẹ́

Sátánì kò fẹ́ ká rí ojúure Ọlọ́run. Kí la lè ṣe tí àárín àwa àti Jèhófà kò fi ní bà jẹ́?

LÁTINÚ ÀPAMỌ́ WA

Inú Ọba Dùn!

Kà nípa bí ọba kan lórílẹ̀-èdè Swaziland ṣe fi hàn pé òun mọyì ẹ̀kọ Bíbélì.