ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ September 2013

Ẹ̀dà yìí jíròrò bá a ṣe lè ṣèpinnu tó bọ́gbọ́n mu, bá a ṣe lè túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà Ọlọ́run àti báwọn ìránnilétí Jèhófà ṣe lè ṣe wá láǹfààní.

Àfiwé Máa Ń Mú Kí Ọ̀rọ̀ Túbọ̀ Yéni

Jésù sábà máa ń lo àfiwé. Kọ́ bó o ṣe lè lo àfiwé láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè lóye òtítọ́.

Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Ṣeé Gbẹ́kẹ̀ Lé

Ìgbà gbogbo ni Jèhófà máa ń lo ìránnilétí láti tọ́ àwọn èèyàn rẹ̀ sọ́nà. Kí nìdí tá a fi lè gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìránnilétí Ọlọ́run lónìí?

Jẹ́ Kí Àwọn Ìránnilétí Jèhófà Máa Múnú Rẹ Dùn

Ǹjẹ́ inú wa máa ń dùn sí àwọn òfin Jèhófà àbí ńṣe la máa ń kà wọ́n sí ìnira nígbà mí ì? Kí ló lè mú ká fọkàn tán àwọn ìránnilétí Jèhófà?

Ǹjẹ́ Ẹ Ti Para Dà?

Kí nìdí tó fi yẹ kí gbogbo Kristẹni fẹ́ láti “para dà”? Kí ló túmọ̀ sí láti para dà? Kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe àwọn ìyípadà tó yẹ?

Máa Fi Ọgbọ́n Ṣe Ìpinnu

Kí la lè ṣe láti rí i pé àwọn ìpinnu wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu? Lẹ́yìn tá a bá ti ṣèpinnu, kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ṣe ohun tá a pinnu?

Iṣẹ́ Ìsìn Aṣáájú-Ọ̀nà Máa Jẹ́ Kó O Túbọ̀ Sún Mọ́ Jèhófà

Kà nípa ọ̀nà mẹ́jọ tí iṣẹ́ aṣáájú-ọ̀nà fi lè mú kó o túbọ̀ sún mọ́ Jèhófà. Kí ló lè mú kó o máa bá a lọ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn tó ń ṣeni láǹfààní yìí?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Bí Jòhánù 11:35 ṣe sọ, kí nìdí tí Jésù fi da omijé lójú kó tó jí Lásárù dìde?