ILÉ ÌṢỌ́ June 2015 | Ṣé Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Tí Rọ́pò Bíbélì?

Ṣé wọ́n tako ara wọn ni àbí wọ́n ń ti ara wọn lẹ́yìn?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Àǹfààní Tí Ìmọ̀ Sáyẹ́ǹsì Ń Ṣe fún Wa

Kí nìdí táwọn kan fi sọ pé “ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì fi hàn dájú pé kò sí Ọlọ́run”?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Ibi Tí Òye Àwọn Onímọ̀ Sáyẹ́ǹsì Mọ

Ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mú kí Carl Sagan sọ pé: “Ti pé èèyàn jẹ́ ọ̀jọ̀gbọ́n kò túmọ̀ sí pé kò lè ṣe àṣìṣe tó bùáyà.”

Bó O Ṣe Lè Dàgbà Lọ́nà Tó Ń Yẹni

Àwọn ohun mẹ́fà kan wà tí Bíbélì sọ, tó máa jẹ́ kó o mu ara rẹ bá ipò tó wà báyìí mu.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Ìran Méje Tó Sin Jèhófà

Kevin Williams sọ ìtàn tó lárinrin nípa bí ìdílé rẹ̀ ṣe fi ìtara ṣe iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run tòótọ́.

Àwọn Wo ni Aṣòdì sí Kristi?

Ṣé ó ti wà lórí ilẹ̀ ayé tipẹ́, àbí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ máa dé ni?

Ohun Tí Bíbélì Sọ

Báwo lo ṣe lè tọ́ àwọn ọmọ rẹ yanjú?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Ṣé Ọgbọ́n Èèyàn Ni Wọ́n Fi Kọ Bíbélì?

Gbọ́ ohun tí Bíbélì fúnra rẹ̀ sọ.