ILÉ ÌṢỌ́ November 2015 | Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?

Ohun tí Bíbélì sọ lè yà ẹ́ lẹ́nu.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Kí Ni Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun?

Ní ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn, Ọlọ́run sọ fún àwọn èèyàn rẹ̀ pé kí wọ́n jagun. Lẹ́yìn náà, Jésù sọ fún kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá wọn. Kí ló fa àyípadà yìí?

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Láyé Ìgbàanì

Ohun pàtàkì mẹ́ta tó jẹ́ kí ogun tí Ọlọ́run fọwọ́ sí yàtọ̀ sáwọn ogun yòókù.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lẹ́yìn tí Jésù Wá Sáyé

Bó tilẹ̀ ojú tí Ọlọ́run fi ń wo ogun kò yí pa dà, àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ kọjá fi hàn pé nǹkan ti yí pa dà.

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Èrò Ọlọ́run Nípa Ogun Lóde Òní

Láìpẹ́, Ọlọ́run máa ja ogun kan tó máa fòpin sí gbogbo ogun.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí nìdí tí Jósẹ́fù fi fá irun rẹ̀ kó tó lọ rí Fáráò? Bíbélì sọ pé Gíríìkì ni bàbá Tímótì. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ilẹ̀ Gíríìsì ni wọ́n bí i sí?

BÍBÉLÌ MÁA Ń YÍ ÌGBÉSÍ AYÉ ÀWỌN ÈÈYÀN PA DÀ

Mo Rò Pé Mò Ń Jayé Orí Mi Ni

Pawel Pyzara máa ń hùwà ipá, ó ń lo oògùn olóró, ó tún ń wá bó ṣe máa dọlọ́rọ̀ nídìí iṣẹ́ amòfin. Ọjọ́ tó bá èèyàn mẹ́jọ jà ni ìgbésí ayé rẹ̀ yí pa dà.

TẸ̀ LÉ ÀPẸẸRẸ ÌGBÀGBỌ́ WỌN

“Ọmọ Mi Olùfẹ́ Ọ̀wọ́n àti Olùṣòtítọ́ Nínú Olúwa”

Kí ló ran Tímótì tó jẹ́ onítìjú èèyàn lọ́wọ́ láti di alábòójútó tó dáńgájíá nínú ìjọ Kristẹni?

Kí Ni Bíbélì Sọ

Tí àwọn òkú bá máa jíǹde, ibo ni wọ́n máa gbé?

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?

Ẹ̀ẹ̀kan péré ni ọ̀rọ̀ náà Amágẹ́dọ́nì fara hàn nínú Bíbélì, àmọ́ Ìwé Mímọ́ sọ̀rọ̀ gan-an nípa ogun tí ọ̀rọ̀ náà tọ́ka sí.