Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

JÍ! No. 5 2017 | Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀​—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là

Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì ká máa múra sílẹ̀ ṣáájú kí àjálù tó dé?

Bíbélì sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù ti fi ara rẹ̀ pa mọ́; aláìní ìrírí tí ó ti gba ibẹ̀ kọjá ti jìyà àbájáde rẹ̀.”​—Òwe 27:12.

Ìwé ìròyìn yìí sọ àwọn nǹkan tó yẹ ká ṣe kí àjálù tó wáyé, nígbà àjálù àti lẹ́yìn tí àjálù bá ti ṣẹlẹ̀.

 

KÓKÓ IWÁJÚ ÌWÉ

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀​—Ohun Tó O Lè Ṣe Láti Gbẹ̀mí Là

Àwọn àbá yìí lè gba ẹ̀mí ẹ àti tàwọn mí ì là.

Bó O Ṣe Lè Máa Ṣọ́ Nǹkan Lò

Wo àwọn ọ̀nà tó o lè gbà máa ṣọ́ àwọn nǹkan lò nínú ilé, tó o bá ń rìnrìn àjò àti nínú ìgbòkègbodò rẹ ojoojúmọ́.

OJÚ ÌWÒYE BÍBÉLÌ

Ogun

Ní ayé àtijọ́, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì máa ń jagun ní orúkọ Ọlọ́run wọn Jèhófà. Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé Ọlọ́run fọwọ́ sí ogun táwọn èèyàn ń jà lónìí?

ÌRÀNLỌ́WỌ́ FÚN ÌDÍLÉ

Kí Làwọn Èèyàn Ń Rí Nínú Eré Tó Léwu?

Inú àwọn ọ̀dọ́ máa ń dùn gan-an tí wọ́n bá ń ṣe irú àwọn eré báyìí, wọ́n máa ń fẹ́ fi hàn pé koko lara àwọn le bó tiẹ̀ jẹ́ pé ohun tí wọ́n ń ṣe lè pa wọ́n lára. Ṣé ó máa ń wu ìwọ náà láti ṣe irú àwọn eré bẹ́ẹ̀?

ILẸ̀ ÀTI ÀWỌN ÈÈYÀN

Ẹ Já Ká Lọ sí Orílẹ̀-Èdè Kazakhstan

Láyé àtijọ́, darandaran ni àwọn èèyàn ilẹ̀ Kazakhstan inú ilé kan tó rí roboto ni wọ́n sábà máa ń gbé. Báwo wa ni ìgbé ayé wọn nísìnyí ṣe jẹ́ ká mọ̀ nípa àṣà ìbílẹ̀ wọn?

TA LÓ ṢIṢẸ́ ÀRÀ YÌÍ?

Ìkarawun ìṣáwùrú

Bí ìkarawun ìṣáwùrú ṣe rí máa ń jẹ́ kó lè dáàbò bo ìṣáwùrú.

Àwọn Nǹkan Míì Tó Wà Lórí Ìkànnì

Kí Nìdí Tí Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Jagun?

Jákèjádò ayé ni wọ́n ti mọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà pé a kì í lọ́wọ́ sí ogun. Kọ́ nípa ìdí tí a kì í fi í lọ́wọ́ sí ogun.

Tí Àjálù Bá Ṣẹlẹ̀, Ìfẹ́ Máa Ń Mú Ká Ṣèrànwọ́

Onírúurú orílẹ̀-èdè làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń ṣèrànwọ́ nígbà àjálù.