ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ May 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti July 9 sí August 5, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Dá Mi Lọ́lá Bí Mo Tiẹ̀ Jẹ́ Ọmọ Tálákà

Ìdílé tálákà ni Samuel Herd ti wá, síbẹ̀ Jèhófà bù kún un nípa tẹ̀mí, kódà ìbùkún náà kọjá àfẹnusọ.

Àlàáfíà​—Báwo Lo Ṣe Lè Ní In?

Inú ayé tó kún fún kòó-kòó jàn-án-jàn-án là ń gbé, torí náà a gbọ́dọ̀ sapá ká tó lè ní àlàáfíà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ràn wá lọ́wọ́.

Jèhófà Nífẹ̀ẹ́ Àwọn Tó Ń “So Èso Pẹ̀lú Ìfaradà”

A lè fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì tá a bá ń wàásù ní ìpínlẹ̀ tí kò fi bẹ́ẹ̀ sèso. Síbẹ̀, iṣẹ́ ìwàásù wa ń múnú Jèhófà dùn.

Kí Nìdí Tá A Fi Ń “Bá A Nìṣó ní Síso Èso Púpọ̀”?

Ó ṣe pàtàkì ká fi ìdí tá a fi ń wàásù sọ́kàn.

Mọ Ọ̀tá Rẹ

A kò ṣe aláìmọ àwọn ète-ọkàn Sátánì tàbí ibi tí agbára rẹ̀ mọ.

Ẹ̀yin Ọ̀dọ́​—Ẹ Dúró Gbọn-In Lòdì sí Èṣù

Gbogbo wa là ń ja ogun tẹ̀mí. Ó sì lè dà bíi pé àwọn ọ̀dọ́ ò lágbára láti borí Sátánì, àmọ́ ìhámọ́ra ogun tẹ̀mí á ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ìkórè Yìí Mà Pọ̀ O!

Ní ìlú kan lórílẹ̀-èdè Ukraine, tá a bá kó èèyàn mẹ́rin jọ, ọ̀kan lára wọn máa jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà!