ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ July 2018

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti September 3 sí 30, 2018 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

WỌ́N YỌ̀ǸDA ARA WỌN TINÚTINÚ

Wọ́n Yọ̀ǹda Ara Wọn Tinútinú​—Ní Myanmar

Kí ló mú kí ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ìlú wọn sílẹ̀ kí wọ́n lè ṣe nínú iṣẹ́ ìkórè tó ń lọ ní Myanmar?

Ojúure Ta Lò Ń Wá?

Kí la rí kọ́ látinú bí Jèhófà ṣe fojúure hàn sáwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́?

Ṣé Jèhófà Lo Tẹjú Mọ́?

A lè kọ́ ẹ̀kọ́ pàtàkì nínú àṣìṣe tí Mósè ṣe.

“Ta Ni Ó Wà ní Ìhà Ọ̀dọ̀ Jèhófà?”

Ìtàn Kéènì, Sólómọ́nì, Mósè àti Áárónì jẹ́ ká rí i pé ìwà ọgbọ́n ló jẹ́ láti wà ní ìhà ọ̀dọ̀ Jèhófà.

A Jẹ́ ti Jèhófà

Ọ̀nà wo la lè gbà dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún àǹfààní tó fún wa láti jẹ́ èèyàn rẹ̀?

Máa Fàánú Hàn sí “Gbogbo Onírúurú Ènìyàn”

O lè fara wé Jèhófà tó o bá ń fàánú hàn sáwọn tó níṣòro, tó o sì ń ṣe gbogbo ohun tó o lè ṣe láti ràn wọ́n lọ́wọ́.

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ṣé a lè sọ pé àwọn méjì tí kì í ṣe tọkọtaya ti dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì tí wọ́n bá jọ sún inú ilé kan náà mọ́jú lábẹ́ ipò tí ń kọni lóminú?