ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ January 2019
Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti March 4 sí April 7, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.
“Má Wò Yí Ká, Nítorí Èmi Ni Ọlọ́run Rẹ”
Ẹ wo ìdí mẹ́ta tí kò fi yẹ ká bẹ̀rù tá a bá kojú ìṣòro.
Máa Yin Jèhófà Nínú Ìjọ
Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti dáhùn nípàdé? Àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o mọ ohun tó ń fà á àti bó o ṣe lè borí rẹ̀.
Báwo Lo Ṣe Lè Dáàbò Bo Ọkàn Rẹ?
Àwọn ọgbọ́n ẹ̀wẹ́ wo ni Sátánì máa ń lò láti sọ ọkàn wa dìbàjẹ́, báwo la sì ṣe lè dáàbò bo ọkàn wa?
Ohun Tí Ètò Ráńpẹ́ Kan Kọ́ Wa Nípa Jésù Ọba Wa
Kí ni Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kọ́ wa nípa ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀, ìgboyà àti ìfẹ́ tí Jésù ní?
Ohun Tí Lílọ sí Ìpàdé Ń Sọ Nípa Wa
Báwo ni ìfẹ́, ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìgboyà ṣe ń mú ká máa pésẹ̀ sípàdé déédéé?
Ẹnì Kan Ṣẹ̀ṣẹ̀ Di Ara Ìgbìmọ̀ Olùdarí
Ka ìtàn nípa Arákùnrin Kenneth Cook, Jr.