ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ February 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti April 8 sí May 5, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Máa Hùwà Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo

Kí ló túmọ̀ sí pé kéèyàn jẹ́ oníwà títọ́, báwo la sì ṣe lè dúró lórí ìpinnu wa láti jẹ́ oníwà títọ́?

Jẹ́ Ọlọ́kàn Tútù Kó O Lè Múnú Jèhófà Dùn

Báwo ni Mósè àti Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ lélẹ̀ tó bá di pé kéèyàn jẹ́ ọlọ́kàn tútù? Àǹfààní wo la máa rí tá a bá jẹ́ ọlọ́kàn tútù?

Kí Nìdí Tó Fi Yẹ Ká Máa Fi Ìmoore Hàn?

Kí la rí kọ́ lára Jèhófà, Jésù àti adẹ́tẹ̀ ará Samáríà kan nípa fífi ìmoore hàn?

Ìfẹ́ àti Ìdájọ́ Òdodo Nílẹ̀ Ísírẹ́lì

Báwo ni Òfin Mósè ṣe jẹ́ ká rí i pé Jèhófà ní ìfẹ́ ó sì máa ń ṣe ìdájọ́ òdodo?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Àpẹẹrẹ Àwọn Ẹni Tẹ̀mí Mú Kí N Fayé Mi Sin Jèhófà

Ka ìtàn ìgbésí ayé Woodworth Mills, kó o sì rí bó ṣe fayé rẹ̀ sin Jèhófà fún nǹkan bí ọgọ́rin (80) ọdún.

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ìgbà wo làwọn Júù bẹ̀rẹ̀ sí í lo sínágọ́gù?