ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ July 2019

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti September 2 sí 29, 2019 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí

Ìsinsìnyí Gan-An Ni Kó O Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Múra Sílẹ̀ fún Inúnibíni

Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ ká sì fìgboyà kojú àtakò? Kí la lè ṣe táwọn èèyàn bá kórìíra wa?

Máa Sin Jèhófà Nìṣó Tí Wọ́n Bá Tiẹ̀ Fòfin De Iṣẹ́ Wa

Kí ló yẹ ká ṣe tí ìjọba bá fòfin de iṣẹ́ wa?

‘Ẹ Lọ, Ẹ Máa Sọ Àwọn Èèyàn Di Ọmọ Ẹ̀yìn’

Kí nìdí tí iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn fi ṣe pàtàkì gan-an? Àwọn nǹkan pàtó wo lá jẹ́ ká ṣe iṣẹ́ náà yọrí?

Bá A Ṣe Lè Wàásù fún Àwọn Tí Kò Ṣe Ẹ̀sìn Kankan

Báwo la ṣe lè mú kí àwọn tí kò ṣe ẹ̀sìn kankan nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run kí wọ́n sì di ọmọ ẹ̀yìn Kristi?

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

Jèhófà Bù Kún Mi Kọjá Ohun Tí Mo Lérò

Ìrírí tí Manfred Tonak ní lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì nílẹ̀ Áfíríkà mú kó mọ béèyàn ṣe ń ní sùúrù, ìtẹ́lọ́rùn àtàwọn ànímọ́ rere mí ì.

Ṣé Èmi Ni Jésù Kú fún Lóòótọ́?

Ṣé ó ti ṣe ẹ́ rí bíi pé o ò wúlò? Kí lá jẹ́ kó o borí èrò yìí?