ILÉ ÌṢỌ́—Ẹ̀DÀ TÓ WÀ FÚN ÌKẸ́KỌ̀Ọ́ March 2020

Àwọn àpilẹ̀kọ tá a máa kẹ́kọ̀ọ́ láti May 4-31, 2020 ló wà nínú Ilé Ìṣọ́ yìí.

Tó O Bá Nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Tó O sì Mọyì Rẹ̀, Wàá Ṣèrìbọmi

Ìfẹ́ tó o ní fún Jèhófà lá mú kó o ṣèrìbọmi. Àmọ́ kí ló lè mú kó o má ṣèrìbọmi?

Ṣé O Ti Ṣe Tán Láti Ṣèrìbọmi?

Ìdáhùn rẹ sáwọn ìbéèrè tó wà nínú àpilẹ̀kọ yìí máa jẹ́ kó o pinnu.

ÌTÀN ÌGBÉSÍ AYÉ

“Àwa Nìyí! Rán Wa!”

Jack àti Marie-Line ṣàlàyé ohun tó mú kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún àti ohun tó jẹ́ kára wọn mọlé bí wọ́n ṣe ń lọ láti ìpínlẹ̀ ìwàásù kan sí òmíì.

Ìgbà Wo Ló Tọ́ Pé Kéèyàn Sọ̀rọ̀?

Wo àwọn àpẹẹrẹ mélòó kan nínú Bíbélì tó jẹ́ ká mọ ìgbà tó yẹ ká sọ̀rọ̀ àti ìgbà tó yẹ ká dákẹ́.

Ẹ Ní Ìfẹ́ Tó Jinlẹ̀ sí Ara Yín

Jésù sọ pé ìfẹ́ làwọn èèyàn fi máa dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. Báwo ni ìfẹ́ ṣe máa mú ká wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn míì, ká máa ṣe aájò àlejò, ká má sì ṣojúsàájú?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Yàtọ̀ sí ohun tí Bíbélì sọ, ẹ̀rí míì wo ló tún fi hàn pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì jẹ́ ẹrú nílẹ̀ Íjíbítì?

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Àwọn wo ni ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì, iṣẹ́ wo ni wọ́n sì ń ṣe?