Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín

Ẹ Máa Dárí Ji Ara Yín

Wà á Jáde:

  1. 1. Ohun rere ló wà lọ́kàn rẹ,

    Inú rere rẹ sì kọjá sísọ.

    Àmọ́ ọ̀rọ̀ tó o sọ yẹn dùn mí gan-an.

    Omi bọ́ lójú mi torí

    Kò rí bó o ṣe rò rárá.

    (ÈGBÈ)

    Kó tó di pé oòrùn yìí wọ̀,

    Jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ yìí yanjú.

    Ká gbàgbé ọ̀rọ̀ àná,

    Kó tán nínú wa.

    Ọ̀rẹ́ ni wá lọ́jọ́kọ́jọ́.

  2. 2. Kì í rọrùn láti jọ ṣiṣẹ́ pọ̀.

    Ọ̀rọ̀ tí ẹnì kan sọ lè dún wá.

    Àfi ká máa dárí jira wa.

    Tẹ́lẹ́bi bá ti mẹ̀bi rẹ̀,

    Ká gbàgbé ló dára jù.

    (ÈGBÈ)

    Kó tó di pé oòrùn yìí wọ̀,

    Jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ yìí yanjú.

    Ká gbàgbé ọ̀rọ̀ àná,

    Kó tán nínú wa.

    Ọ̀rẹ́ ni wá lọ́jọ́kọ́jọ́.

    (ÀSOPỌ̀)

    Kò sọ́rọ̀ tàbí ‘ṣe tó lè yà wá. Ṣebí ìfẹ́ ló so wá pọ̀.

    Jọ̀ọ́, jẹ́ kó tán, gbé e kúrò lọ́kàn;

    Bọ́rẹ̀ẹ́ tòótọ́ ṣe ń ṣe nìyẹn.

    (ÈGBÈ)

    Kó tó di pé oòrùn yìí wọ̀,

    Jẹ́ ká rí i pé ọ̀rọ̀ yìí yanjú.

    Ká gbàgbé ọ̀rọ̀ àná,

    Kó tán nínú wa.

    Látọkàn wá ló gbọ́dọ̀ jẹ́.

    Ká fìfẹ́ hàn, ká dárí ji ara wa.