Ó Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dé Tán
Wà á jáde:
1. Ò ń gbọ́ tẹ́yẹ ń kọrin tó dùn,
Tójú ọjọ́ sì rẹwà.
Bó o sì ṣe ń lọ lójú ọ̀nà,
O wá rí i bóòrùn tó yọ ṣe ń tàn.
Ò ń káwọn òkú káàbọ̀,
Ó sì ń yà ọ́ lẹ́nu gan-an
Pó o wà ní Párádísè;
Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.
2. Ilé kan wà ní ìsàlẹ̀
Ìkan wà lórí òkè.
Àwọn kan ń kọrin létídò
Bí omi tó mọ́ lóló ṣe ń ṣàn.
Àkókò ìkórè tó.
Ẹ jẹ́ kí ‘kórè bẹ̀rẹ̀.
A ti wà láyé tuntun;
Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.
(ÀSOPỌ̀)
Ó yẹ ká sọ fáwọn èèyàn
Nípa ìrètí tá a ní yìí
Kò sẹ́kún mọ́, kò síkú mọ́.
Ará dọ̀tun, ayé tuntun.
3. Inú gbogbo èèyàn ló ń dùn.
Ò ń gbọ́ òórùn tó tura.
O wá ń kí àwọn èèyàn rẹ.
Kò sẹ́ṣẹ̀, èèyàn ti di pípé.
A dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà
Torí ‘fẹ tó ní sí wa.
Ìbùkún ńlá ló sì jẹ́
Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.
(ÀSOPỌ̀)
Lójoojúmọ́, mò ń sọ pé:
“Inú mi dùn pé mo rí ọ!”
Ṣe ló dà bí àlá sí mi,
Pé mo lè tún pa dà rí ọ.
4. Mo ti ń fojú sọ́nà
Láti rí ayé tuntun.
Jèhófà ló ṣèlérí yìí.
Ọ̀rọ̀ rẹ̀ kò ní lọ láìṣẹ.
Tí n bá rántí ayé tuntun,
Ó máa ń fọkàn mi balẹ̀.
Mo ti ń retí ọjọ́ náà,
Ó sì ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dé tán.