Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìfẹ́ Tòótọ́

Ìfẹ́ Tòótọ́

Wà á jáde:

  1. 1. Ẹ̀bùn kan wà t’Ọlọ́run fún wa,

    Ẹ̀bùn ìfẹ́ ni ẹ̀bùn yìí.

    B’ọkùnrin àtobìnrin pàdé,

    Àkókò ayọ̀ ńlá ló máa ń jẹ́.

    (ÈGBÈ)

    Tí a bá fẹ́ gbádùn ẹ̀bùn àtàtà yìí,

    Ká máa rántí pé

    Jèhófà

    La gbọ́dọ̀ fi ṣatọ́nà, ká má bàa ṣìṣe,

    Ìfẹ́ òtítọ́ mo ní sí ẹ

    Olólùfẹ́ mi,

    Onítèmi.

  2. 2. Bí ‘ṣòro bá dé,

    A ò ní jẹ́ kífẹ̀ẹ́ wa di tútù.

    A ó máa jẹ́ kífẹ̀ẹ́ wa lágbára sí i.

    A ò ní jẹ́ kí ohunkóhun yà wá.

    Lọ́lá Jèhófà.

    (ÈGBÈ)

    Tí a bá fẹ́ gbádùn ẹ̀bùn àtàtà yìí

    Ká máa rántí pé

    Jèhófà

    La gbọ́dọ̀ fi ṣatọ́nà, ká má bàa ṣìṣe,

    Ìfẹ́ òtítọ́ mo ní sí ẹ

    Olólùfẹ́ mi,

    Onítèmi.

    (ÀSOPỌ̀)

    Kífẹ̀ẹ́ wa má ṣe yẹ̀ láé.

    Ìfẹ́ látọ̀dọ́ Jèhófà Ọlọ́run.

    Ìfẹ́ tòótọ́ ‘lágbára gan-an bí ikú.’

    ‘Ìwọ legungun mi, àtẹran ara mi’

    Mo ti rí i pé obìnrin àtàtà ni ẹ́.

    Ìfẹ́ rẹ kò ní yẹ̀ lọ́kàn mi.

  3. 3. Onítèmi mo nífẹ̀ẹ́ rẹ

    Ìfẹ́ òtítọ́ ni mo ní sí ẹ.

    Ọpẹ́ f’Ọlọ́run pé mo pàdé rẹ.

    Mo dúpẹ́ péwọ nìyàwó mi.

    Mo dúpẹ́.

    (ÈGBÈ)

    Tí a bá fẹ́ gbádùn ẹ̀bùn àtàtà yìí,

    Ká máa rántí pé

    Jèhófà

    La gbọ́dọ̀ fi ṣatọ́nà, ká má bàa ṣìṣe,

    Ìfẹ́ òtítọ́ mo ní sí ẹ

    Olólùfẹ́ mi,

    Mo nifẹ́ẹ̀ rẹ.

    Ìfẹ́ òtítọ́ mo ní sí ẹ

    Olólùfẹ́ mi,