Ayé Tuntun
Wà á jáde:
1. Ronú nípa báyé ṣe máa rí.
Nígbà táyé tuntun tá à ń retí bá dé.
Àwọn ‘mọdé ń ṣeré
Kò sí ohun tó ń fa ìbẹ̀rù mọ́.
Àwọn tó máa gbénú ayé tuntun
Làwọn onígbọràn, èèyàn àlàáfíà.
Títí ayérayé ni.
Àlàáfíà tí a ti ń retí dé!
Jáà yóò ṣìkẹ́ wa
Lábẹ́ ìjọba Ọmọ rẹ̀,
Nínú ayé tuntun.
(ÈGBÈ)
Ìrètí ń múnú wa dùn.
Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀.
Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.
À ń retí ìbùkún
Nínú ayé tuntun.
2. Tí a bá dénú ayé tuntun
Lórí òkè, lórí ilẹ̀, níbi odò.
Ìtura yóò gbayé.
Ṣàdédé lo rẹ́nì kan tó ń bọ̀,
Ọjọ́ pẹ́ tẹ́ ẹ ti ríra.
Ẹ̀yin méjèèjì wá dì mọ́ra
Ẹ jọ ń sunkún ayọ̀
O mọ̀ pé onítọ̀hún ti kú tẹ́lẹ̀.
Jèhófà ti jí
Ẹni yẹn dìde!
Sínú ayé tuntun.
(ÈGBÈ)
Ìrètí ń múnú wa dùn.
Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀.
Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.
À ń retí ìbùkún
Nínú ayé tuntun.
(ÀSOPỌ̀)
Ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ
Kò ní lọ láìṣẹ, ó di dandan.
Gbogbo ìfẹ́ Jèhófà ni
Ó máa ṣẹ pátápátá ní ayé.
(ÈGBÈ)
Ìrètí ń múnú wa dùn.
Ìrètí máa ń fọkàn wa balẹ̀
Ṣe ni ìrètí wa ń tàn bí oòrùn.
À ń retí ìbùkún
Nínú ayé tuntun,
Nínú ayé tuntun,
Nínú ayé tuntun,
Nínú ayé tuntun.