Fi Àwọn Ìlànà Bíbélì Sílò

Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run máa ń kọ́ wa láwọn ìlànà tá a lè ronú lé lórí tá a bá fẹ́ ṣe ohunkóhun. Wo àwọn àpẹẹrẹ kan tó jẹ́ ká mọ bí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó wà nínú Bíbélì ṣe wúlò tó.

Wá Àwọn Ọ̀rẹ́ ní Ibi tí O Ò Lérò

Kò sóhun tó burú nínú kéèyàn fẹ́ lọ́rẹ̀ẹ́. Àmọ́ tó o bá ń wá ọ̀rẹ́ gidi, àwọn ìlànà Bíbélì wo ló lè ràn ẹ́ lọ́wọ́?

Jèhófà Ọlọ́run Máa Ràn Ẹ́ Lọ́wọ́

Kò dìgbà tó o bá di ẹni pípé kó o tó lè sin Ọlọ́run. Ó fẹ́ kó o ṣàṣeyọrí, ó máa tì ẹ́ lẹ́yìn, á sì ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Wàá Jẹ́ Ọlọ́gbọ́n Tó O Bá Ń Gbàmọ̀ràn

Ìmọ̀ran ló yẹ ká ṣiṣẹ́ lé lórí kì í ṣe ọ̀nà tẹ́ni yẹn gbà bá wa sọ̀rọ̀. Ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n tí alàgbà kan bá fún wa jẹ́ ẹ̀rí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa.