Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ẹ̀yin òbí, ẹ fi àwọn ìtàn yìí kọ́ àwọn ọmọ yín ní àwọn ẹ̀kọ́ pàtàkì látinú Bíbélì.

Ìbẹ̀rẹ̀ Ìwé

Àwọn ọ̀rọ̀ inú ìwé Diutarónómì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti tọ́ àwọn ọmọ ẹ.

Ẹ̀KỌ́ 1

Inú Wa Dùn Láti Mọ Àṣírí Kan

Bíbélì sọ àṣírí pàtàkì kan, ó pè é ní “àṣírí ọlọ́wọ̀.” Ṣé wàá fẹ́ mọ àṣírí yìí?

Ẹ̀KỌ́ 2

Rèbékà Mú Inú Jèhófà Dùn

Kí la lè ṣe láti fi ìwà jọ Rèbékà? Ka ìtàn rẹ̀ kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa rẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 3

Ráhábù Gba Jèhófà Gbọ́

Kà nípa bí Jèhófà ṣe gba Ráhábù àti ìdílé rẹ̀ là nígbà tí Jẹ́ríkò pa run.

Ẹ̀KỌ́ 4

Ó Mú Inú Bàbá Rẹ̀ àti Inú Jèhófà Dùn

Ìlérí wo ni ọmọbìnrin Jẹ́fútà mú ṣẹ? Báwo la ṣe lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀?

Ẹ̀KỌ́ 5

Sámúẹ́lì Ń Bá A Lọ Láti Máa Ṣe Ohun tí Ó Dára

Báwo lo ṣe lè fìwà jọ Sámúẹ́lì, kó o máa ṣe ohun tó tọ́, tí àwọn èèyàn bá tiẹ̀ ń ṣe ohun tí ò dáa?

Ẹ̀KỌ́ 6

Dáfídì Kò Bẹ̀rù

Ka ìtàn inú Bíbélì tó dùn yìí kó o lè mọ ohun tó mú kí Dáfídì nígboyà tó bẹ́ẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 7

Ǹjẹ́ Ẹ̀rù Máa Ń Bà Ẹ́ Tó O Bá Dá Wà?

Kí ni Jèhófà sọ fún Èlíjà nígbà tó dá wà? Kí lo lè kọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Èlíjà?

Ẹ̀KỌ́ 8

Jòsáyà Ní Àwọn Ọ̀rẹ́ Rere

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé kò rọrùn rárá fún Jòsáyà láti ṣe ohun tó tọ́. Wo bí àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ ṣe ràn án lọ́wọ́.

Ẹ̀KỌ́ 9

Jeremáyà Ń Bá A Lọ Láti Sọ̀rọ̀ Nípa Jèhófà

Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n fi Jeremáyà ṣe yẹ̀yẹ́, tí wọ́n sì bínú sí i, kí ló mú kó máa bá a lọ láti sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run?

Ẹ̀KỌ́ 10

Jésù Máa Ń Ṣègbọràn ní Gbogbo Ìgbà

Kì í ṣe gbogbo ìgbà ló máa ń rọrùn láti ṣègbọràn sí àwọn òbí rẹ. Wo bí àpẹrẹ Jésù ṣe lè ràn ẹ́ lọ́wọ́.

Ẹ̀KỌ́ 11

Wọ́n Kọ Ìwé Nípa Jésù

Kọ́ nípa àwọn mẹ́jọ tó kọ Bíbélì lára àwọn tó jọ gbé ayé pẹ̀lú Jésù, tí wọ́n sì kọ̀wé nípa ìgbésí ayé rẹ̀.

Ẹ̀KỌ́ 12

Onígboyà Ni Mọ̀lẹ́bí Pọ́ọ̀lù

Ọ̀dọ́kùnrin yìí gba ẹ̀mí mọ̀lẹ́bí rẹ̀ là. Kí ló ṣe?

Ẹ̀KỌ́ 13

Tímótì Fẹ́ Ran Àwọn Èèyàn Lọ́wọ́

Báwo ni ayé rẹ ṣe lè dún bí oyin bíi ti Tímótì?

Ẹ̀KỌ́ 14

Ìjọba Kan Tó Máa Ṣàkóso Gbogbo Ayé

Báwo ni ayé ṣe máa rí tí Jésù bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso? Ṣé wàá fẹ́ wà níbẹ̀?