Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni
Ìwé yìí máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti suwọ̀n sí i nínú kíkàwé àti kíkọ́ni.
Lẹ́tà Látọ̀dọ̀ Ìgbìmọ̀ Olùdarí
À ń kọ́ àwọn èèyàn ní ohun tó ṣe pàkàtì jù lọ.
Ẹ̀KỌ́ 2
Sọ̀rọ̀ Bí Ẹni Ń Báni Fọ̀rọ̀ Wérọ̀
Tó o bá ń sọ̀rọ̀ bí ẹni ń fọ̀rọ̀ wérọ̀, ara á tu àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀, á sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ wọ́n lọ́kàn.
Ẹ̀KỌ́ 3
Lo Ìbéèrè Bó Ṣe Yẹ
Fi ọgbọ́n béèrè àwọn ìbéèrè tó máa jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ nífẹ̀ẹ́ sí ọ̀rọ̀ rẹ, tó sì máa gbé àwọn kókó pàtàkì inú ọ̀rọ̀ rẹ yọ.
ÈKỌ́ 4
Nasẹ̀ Ìwé Mímọ́ Lọ́nà Tó Yẹ
Wo bó o ṣe lè múra ọkàn àwọn èèyàn sílẹ̀ kó o tó ka ẹsẹ Ìwé Mímọ́.
Ẹ̀KỌ́ 5
Kàwé Lọ́nà Tó Tọ́
Tá a bá fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa Jèhófà, ó ṣe pàtàkì pé ká máa kàwé lọ́nà tó tọ́.
Ẹ̀KỌ́ 6
Jẹ́ Kí Ìdí Tó O Fi Ka Ìwé Mímọ́ Ṣe Kedere
Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí i kedere bí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó o kà ṣe bá kókó tó ò ń sọ̀rọ̀ lé lórí mu.
Ẹ̀KỌ́ 7
Ọ̀rọ̀ Tó Péye Tó sì Ń Yíni Lérò Pa Dà
Tí ọ̀rọ̀ wa bá péye tó sì ń yíni lérò pa dà, ó máa jẹ́ kí àwọn tá à ń bá sọ̀rọ̀ gbà pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ wa.
Ẹ̀KỌ́ 8
Àpèjúwe Tó Ń Kọ́ni Lẹ́kọ̀ọ́
Wàá mú kí ọ̀nà tó ò ń gbà kọ́ni dára sí i tó o bá ń lo àwọn àpèjúwe tó rọrùn, tó máa fa àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ mọ́ra, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n rí ẹ̀kọ́ pàtàkì kọ́.
Ẹ̀KỌ́ 9
Lo Ohun Tá A Lè Fojú Rí Lọ́nà Tó Dára
Tó o bá lo ohun tá a lè fojú ri, àwọn èèyàn ò ní tètè gbàgbé ọ̀rọ̀ rẹ.
Ẹ̀KỌ́ 10
Yí Ohùn Pa Dà Bó Ṣe Yẹ
Yí bó o ṣe ń yára sọ̀rọ̀ àti bó o ṣe ń rọra sọ̀rọ̀ pa dà, yí ìró ohùn pa dà, kó o sì jẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ wọ̀ wọ́n lọ́kàn, kí wọ́n sì ṣe ohun tó yẹ.
Ẹ̀KỌ́ 11
Ìtara
Tá a bá ń fi ìtara sọ̀rọ̀, ó fi hàn pé à ń sọ̀rọ̀ látọkàn wá, ìyẹn ò sì ní jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa sú àwọn tó ń gbọ́ wa.
Ẹ̀KỌ́ 12
Ọ̀yàyà àti Ìfọ̀rọ̀rora-Ẹni-Wò
Tó o bá fi ìmọ̀lára tó yẹ sọ̀rọ̀, àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ á rí i pé o nífẹ̀ẹ́ wọn.
Ẹ̀KỌ́ 13
Sọ Bí Ọ̀rọ̀ Rẹ Ṣe Wúlò
Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ rí bí ohun tó ò ń sọ ṣe kan ìgbésí ayé wọn, kó o sì sọ bí wọ́n ṣe máa lò ó lọ́nà tó ṣàǹfààní.
Ẹ̀KỌ́ 14
Jẹ́ Kí Kókó Ọ̀rọ̀ Fara Hàn Kedere
Jẹ́ kí àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ máa fọkàn bá ẹ lọ, jẹ́ kó ṣe kedere bí kókó ọ̀rọ̀ kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ ohun tó o fẹ́ kí ọ̀rọ̀ rẹ ṣe àti ohun tí ọ̀rọ̀ rẹ dá lé.
Ẹ̀KỌ́ 15
Fi Ìdánilójú Sọ̀rọ̀
Fi ìdánilójú sọ̀rọ̀. Sọ̀rọ̀ lọ́nà tó fi hàn pé o gbà pé ọ̀rọ̀ náà ṣe pàtàkì.
Ẹ̀KỌ́ 16
Jẹ́ Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Gbéni Ró Kó sì Ṣàǹfààní
Sọ ọ̀rọ̀ tó ń gbéni ró, má ṣe fi ìkanra sọ̀rọ̀. Jẹ́ kí àwọn èèyàn rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tuni lara, ó sì ń fini lọ́kàn balẹ̀.
Ẹ̀KỌ́ 18
Jẹ́ Kí Àwọn Èèyàn Rí Ẹ̀kọ́ Kọ́ Nínú Ọ̀rọ̀ Rẹ
Sọ ohun tó máa mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ ronú jinlẹ̀, tó sì máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé àwọn rí ẹ̀kọ́ gidi kọ́.
Ẹ̀KỌ́ 19
Kí Ọ̀rọ̀ Rẹ Wọni Lọ́kàn
Mú kí àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run àti Bíbélì ọ̀rọ̀ rẹ̀.
Ẹ̀KỌ́ 20
Ìparí Ọ̀rọ̀ Tó Dára
Ìparí ọ̀rọ̀ tó dara máa ran àwọn tó ò ń bá sọ̀rọ̀ láti fi ohun tí wọ́n gbọ́ sọ́kàn, kí wọ́n lè ṣe ohun tó yẹ.
Máa Ṣàkọsílẹ̀ Ìtẹ̀síwájú Rẹ
Máa ṣàkọsílẹ̀ ìtẹ̀síwájú rẹ bó o ṣe sùnwọ̀n sí i nínú kíkàwé àti kíkọ́ni.
O Tún Lè Wo
FÍDÍÒ ALÁPÁ-PÚPỌ̀
Tẹra Mọ́ Kíkàwé àti Kíkọ́ni—Fídíò
Kọ́ àwọn nǹkan pàtàkì tó máa jẹ́ kó o lè kàwé, kó o sì lè kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ lọ́nà tó dára.