Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ
Wo fídíò nípa àwọn ọ̀dọ́ yíká ayé. Wọ́n sọ àwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ àti bí wọ́n ṣe ń borí wọn.
Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ Nípa Fóònù
Fóònù ni ọ̀pọ̀ ọ̀dọ́ fi máa ń mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀ láwùjọ. Àǹfààní wo ló wà nínú kéèyàn ní fóònù, ewu wo ló sì wà níbẹ̀?
Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ Nípa Fífi Nǹkan Falẹ̀
Gbọ́ ohun táwọn ọ̀dọ́ sọ nípa ewu tó wà nínú kéèyàn máa fi nǹkan falẹ̀ àti àǹfààní tó wà nínú kéèyàn máa jára mọ́ ohun tó ní í ṣe.
Ohun Táwọn Ọ̀dọ́ Sọ Nípa Owó
Kẹ́kọ̀ọ́ nípa bó o ṣe lè fowó pa mọ́, bó ṣe yẹ kó o ná an àti bó ò ṣe ní sọ ara rẹ di ẹrú owó.
Ohun Táwọn Ojúgbà Rẹ Sọ Nípa Fífi Ọ̀rànyàn Báni Tage
Gbọ́rọ̀ lẹ́nu àwọn ọ̀dọ́ márùn-ún nípa fífi ọ̀ranyàn báni tage àtohun tó o lè ṣe tó bá ṣẹlẹ̀ sí ẹ.
Àwọn Ọ̀dọ́ Sọ̀rọ̀ Nípa Ìlera
Ṣé ó máa ń ṣòro fún ẹ láti ṣọ́ ohun tí wàá jẹ, kó o sì ṣeré ìmárale? Nínú fídíò yìí, àwọn ọ̀dọ́ sọ̀rọ̀ nípa ohun tí wọ́n máa ń ṣe kí wọ́n lè nílera tó dáa.
Àwọn Ọ̀dọ́ Sọ Pé Ọlọ́run Wà Lóòótọ́
Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ ohun tó jẹ́ kó dá wọn lójú pé Ẹlẹ́dàá kan wà lóòótọ́ nínu fídíò oníṣẹ̀ẹ́jú mẹ́ta yìí.
Àwọn Ọ̀dọ́ Sọ̀rọ̀ Nípa Kíka Bíbélì
Ìwé kíkà kì í fìgbà gbogbo rọrùn, àmọ́ téèyàn bá ń ka Bíbélì, ó lérè. Àwọn ọ̀dọ́ mẹ́rin ṣàlàyé àǹfààní tí wọ́n ń rí bí wọ́n ṣe ń ka Bíbélì.
Jẹ́ Kí Ohun Tó O Gbà Gbọ́ Dá Ẹ Lójú—Ṣé Ìlànà Ọlọ́run Ni Màá Tẹ̀ Lé àbí Èrò Ara Mi?
Àwọn ọ̀dọ́ kan sọ ohun tí wọ́n ṣe kí wọ́n má bàa jìyà àbájáde ìwà tí ọ̀pọ̀ ọmọ kíláàsì wọn ń hù.
Báwo Ni Mo Ṣe Lè Ṣàtúnṣe?
Ohun tó yẹ kó o ṣe lè má le tó bó o ṣe rò.
Cameron Gbé Ìgbésí Ayé Tó Dára Jù Lọ
Ṣé o fẹ́ káyé ẹ nítumọ̀? Gbọ́ bí Cameron ṣe ń sọ bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó ní ibi tí kò lérò.