Sámúẹ́lì Kìíní 4:1-22

  • Àwọn Filísínì gba Àpótí náà (1-11)

  • Élì àti àwọn ọmọ rẹ̀ kú (12-22)

4  Sámúẹ́lì bá gbogbo Ísírẹ́lì sọ̀rọ̀. Lẹ́yìn náà, Ísírẹ́lì jáde lọ pàdé àwọn Filísínì láti bá wọn jà; wọ́n pàgọ́ sí ẹ̀gbẹ́ Ẹbinísà, àwọn Filísínì sì pàgọ́ sí Áfékì.  Àwọn Filísínì tò lọ́wọ̀ọ̀wọ́ láti bá Ísírẹ́lì jà, àmọ́ ìjà náà yíwọ́, àwọn Filísínì ṣẹ́gun Ísírẹ́lì, wọ́n pa nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin (4,000) ọkùnrin lójú ogun ní pápá.  Nígbà tí àwọn èèyàn náà pa dà sí ibùdó, àwọn àgbààgbà Ísírẹ́lì sọ pé: “Kí ló dé tí Jèhófà fi jẹ́ kí àwọn Filísínì ṣẹ́gun wa lónìí?*+ Ẹ jẹ́ kí a lọ gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà láti Ṣílò,+ kí ó lè wà lọ́dọ̀ wa, kí ó sì gbà wá lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá wa.”  Nítorí náà, wọ́n rán àwọn èèyàn lọ sí Ṣílò, láti ibẹ̀, wọ́n gbé àpótí májẹ̀mú Jèhófà Ọlọ́run àwọn ọmọ ogun, ẹni tó ń jókòó lórí* àwọn kérúbù.+ Àwọn ọmọkùnrin Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì+ sì wà níbẹ̀ pẹ̀lú àpótí májẹ̀mú Ọlọ́run tòótọ́.  Gbàrà tí àpótí májẹ̀mú Jèhófà dé sí ibùdó, gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì hó yèè, tí ilẹ̀ fi mì tìtì.  Nígbà tí àwọn Filísínì gbọ́ ìró wọn, wọ́n sọ pé: “Kí ló fa irú ariwo yìí ní ibùdó àwọn Hébérù?” Níkẹyìn, wọ́n wá mọ̀ pé Àpótí Jèhófà ti dé sí ibùdó.  Ẹ̀rù ba àwọn Filísínì gan-an, wọ́n sọ pé: “Ọlọ́run ti dé sí ibùdó!”+ Ni wọ́n bá sọ pé: “A ti dáràn, nítorí irú èyí ò ṣẹlẹ̀ rí!  A ti dáràn! Ta ló máa gbà wá lọ́wọ́ Ọlọ́run títóbi yìí? Ọlọ́run yìí ló pa àwọn ará Íjíbítì lóríṣiríṣi ọ̀nà ní aginjù.+  Ẹ jẹ́ onígboyà, kí ẹ sì ṣe bí ọkùnrin, ẹ̀yin Filísínì, kí ẹ má bàa sin àwọn Hébérù bí wọ́n ṣe sìn yín.+ Ẹ ṣe bí ọkùnrin, kí ẹ sì jà!” 10  Torí náà, àwọn Filísínì jà, wọ́n ṣẹ́gun Ísírẹ́lì,+ kálukú wọn sì sá lọ sí ilé rẹ̀. Ìpakúpa náà pọ̀; ọ̀kẹ́ kan ààbọ̀ (30,000) àwọn ọmọ ogun tó ń fẹsẹ̀ rìn ló kú lára àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. 11  Yàtọ̀ síyẹn, wọ́n gba Àpótí Ọlọ́run, àwọn ọmọ Élì méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì sì kú.+ 12  Lọ́jọ́ yẹn, ọkùnrin ará Bẹ́ńjámínì kan sá wá sí Ṣílò láti ojú ogun, aṣọ rẹ̀ ti ya, iyẹ̀pẹ̀ sì wà lórí rẹ̀.+ 13  Nígbà tí ọkùnrin náà dé, Élì wà lórí ìjókòó lẹ́gbẹ̀ẹ́ ọ̀nà tó ń ṣọ́nà, ọkàn rẹ̀ ò balẹ̀ nítorí Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.+ Ọkùnrin náà lọ sínú ìlú láti ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀, gbogbo ìlú náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í sunkún. 14  Nígbà tí Élì gbọ́ igbe ẹkún náà, ó béèrè pé: “Kí ló fa irú ariwo tí mò ń gbọ́ yìí?” Ní kíá, ọkùnrin náà wọlé, ó sì ròyìn ohun tó ṣẹlẹ̀ fún Élì. 15  (Ní àkókò yẹn, Élì jẹ́ ẹni ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-ún [98], ojú rẹ̀ là sílẹ̀, àmọ́ kò rí nǹkan kan.)+ 16  Ọkùnrin náà wá sọ fún Élì pé: “Ojú ogun ni mo ti ń bọ̀! Òní yìí gan-an ni mo sá kúrò lójú ogun.” Ni Élì bá bi í pé: “Kí ló ṣẹlẹ̀, ọmọ mi?” 17  Ọkùnrin tó mú ìròyìn náà wá sì sọ pé: “Ísírẹ́lì ti sá níwájú àwọn Filísínì, wọ́n sì ti ṣẹ́gun àwọn èèyàn wa lọ́nà tó kàmàmà+ àti pé àwọn ọmọ rẹ méjèèjì, Hófínì àti Fíníhásì ti kú,+ wọ́n sì ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.”+ 18  Ní gbàrà tó mẹ́nu kan Àpótí Ọlọ́run tòótọ́, Élì ṣubú sẹ́yìn láti orí ìjókòó tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ẹnubodè, ọrùn rẹ̀ ṣẹ́, ó sì kú, nítorí pé ó ti darúgbó, ó sì sanra. Ogójì (40) ọdún ló fi ṣèdájọ́ Ísírẹ́lì. 19  Aya ọmọ rẹ̀, ìyẹn ìyàwó Fíníhásì wà nínú oyún, kò sì ní pẹ́ bímọ. Nígbà tó gbọ́ ìròyìn pé wọ́n ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àti pé bàbá ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀ ti kú, ó tẹ̀ ba, lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ ó bẹ̀rẹ̀ sí í rọbí, ó sì bímọ. 20  Bí ó ṣe ń kú lọ, àwọn obìnrin tó dúró tì í sọ pé: “Má bẹ̀rù, nítorí ọkùnrin lo bí.” Kò dáhùn, kò sì fiyè sí i.* 21  Ṣùgbọ́n ó pe ọmọ náà ní Íkábódì,*+ ó ní: “Ògo ti kúrò ní Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn,”+ ó ń tọ́ka sí bí wọ́n ṣe gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́ àti ohun tó ṣẹlẹ̀ sí bàbá ọkọ rẹ̀ àti ọkọ rẹ̀.+ 22  Ó sọ pé: “Ògo ti kúrò ní Ísírẹ́lì lọ sí ìgbèkùn, nítorí wọ́n ti gba Àpótí Ọlọ́run tòótọ́.”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Ní Héb., “tí Jèhófà fi ṣẹ́gun wa nípasẹ̀ àwọn Filísínì lónìí?”
Tàbí kó jẹ́, “láàárín.”
Tàbí “kò sì fọkàn sí i.”
Ó túmọ̀ sí “Ibo Ni Ògo Wà?”