Léfítíkù 17:1-16

  • Àgọ́ ìjọsìn, ibi tí wọ́n ti ń rúbọ (1-9)

  • Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ (10-14)

  • Ìlànà nípa àwọn ẹran tó ti kú (15, 16)

17  Jèhófà ń bá ọ̀rọ̀ tó ń sọ fún Mósè lọ pé:  “Sọ fún Áárónì àti àwọn ọmọ rẹ̀ àti gbogbo àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé, ‘Ohun tí Jèhófà pa láṣẹ nìyí:  “‘“Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì bá pa akọ màlúù tàbí ọmọ àgbò tàbí ewúrẹ́ nínú ibùdó tàbí tó pa á ní ẹ̀yìn ibùdó,  dípò kó mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi ṣe ọrẹ fún Jèhófà níwájú àgọ́ ìjọsìn Jèhófà, ọkùnrin náà máa jẹ̀bi ẹ̀jẹ̀. Ó ti ta ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀, ṣe ni kí ẹ pa á, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.  Èyí máa mú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì mú ẹbọ wọn, tí wọ́n ń rú nínú pápá gbalasa wá fún Jèhófà, sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, sọ́dọ̀ àlùfáà. Kí wọ́n fi nǹkan wọ̀nyí rúbọ bí ẹbọ ìrẹ́pọ̀ sí Jèhófà.+  Kí àlùfáà wọ́n ẹ̀jẹ̀ ẹran náà sórí pẹpẹ Jèhófà ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé, kó sì mú kí ọ̀rá ẹran náà rú èéfín sí Jèhófà láti mú òórùn dídùn* jáde.+  Torí náà, kí wọ́n má ṣe rú ẹbọ mọ́ sí àwọn ẹ̀mí èṣù tó rí bí ewúrẹ́,*+ èyí tí wọ́n ń bá ṣèṣekúṣe.+ Kí èyí jẹ́ àṣẹ tó máa wà títí lọ fún yín, jálẹ̀ àwọn ìran yín.”’  “Kí o sọ fún wọn pé, ‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá rú ẹbọ sísun tàbí tó rúbọ,  tí kò sì mú un wá sí ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé láti fi rúbọ sí Jèhófà, kí ẹ pa ẹni náà, kí ẹ lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀.+ 10  “‘Tí ọkùnrin kankan ní ilé Ísírẹ́lì tàbí tí àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín bá jẹ ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí, ó dájú pé mi ò ní fi ojú rere wo ẹni* tó ń jẹ ẹ̀jẹ̀, èmi yóò sì pa á, kí n lè mú un kúrò láàárín àwọn èèyàn rẹ̀. 11  Torí inú ẹ̀jẹ̀+ ni ẹ̀mí* ẹran wà, èmi fúnra mi sì ti fi sórí pẹpẹ+ fún yín kí ẹ lè ṣe ètùtù fún ara yín,* torí ẹ̀jẹ̀ ló ń ṣe ètùtù+ nípasẹ̀ ẹ̀mí* tó wà nínú rẹ̀. 12  Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ìkankan* nínú yín ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀, àjèjì kankan tó ń gbé láàárín yín+ ò sì gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀.”+ 13  “‘Tí ọmọ Ísírẹ́lì kan tàbí àjèjì kan tó ń gbé láàárín yín bá ń ṣọdẹ, tó sì mú ẹran ìgbẹ́ tàbí ẹyẹ tí ẹ lè jẹ, ó gbọ́dọ̀ da ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ jáde,+ kó sì fi erùpẹ̀ bò ó. 14  Torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran, torí pé ẹ̀mí* wà nínú ẹ̀jẹ̀ náà. Ìdí nìyẹn tí mo fi sọ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ẹ̀jẹ̀ ẹran èyíkéyìí, torí ẹ̀jẹ̀ ni ẹ̀mí* gbogbo onírúurú ẹran. Kí ẹ pa ẹnikẹ́ni tó bá jẹ ẹ́.”+ 15  Tí ẹnikẹ́ni* bá jẹ òkú ẹran tàbí èyí tí ẹran inú igbó fà ya,+ ì báà jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ tàbí àjèjì ló jẹ ẹ́, kó fọ aṣọ rẹ̀, kó fi omi wẹ̀, kó sì di aláìmọ́ títí di alẹ́;+ lẹ́yìn náà, á di mímọ́. 16  Àmọ́ tí kò bá fọ̀ wọ́n, tí kò sì wẹ̀,* yóò jìyà ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀.’”+

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “àwọn ewúrẹ́.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn yín.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “Ọkàn kankan.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn.”
Tàbí “ọkàn èyíkéyìí.”
Ní Héb., “wẹ ẹran ara rẹ̀.”