Léfítíkù 3:1-17

  • Ẹbọ ìrẹ́pọ̀ (1-17)

    • Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀ (17)

3  “‘Tí ohun tó mú wá bá jẹ́ ẹbọ ìrẹ́pọ̀,*+ tó sì jẹ́ látinú ọ̀wọ́ ẹran ló ti fẹ́ mú un wá, yálà akọ tàbí abo, ẹran tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá ni kó mú wá fún Jèhófà.  Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n pa á ní ẹnu ọ̀nà àgọ́ ìpàdé; kí àwọn ọmọ Áárónì, àwọn àlùfáà, sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.  Kó fi lára ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà:+ ọ̀rá+ tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká  àti kíndìnrín méjèèjì pẹ̀lú ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú rẹ̀. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀, pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ ẹran náà.  Kí àwọn ọmọ Áárónì mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ, lórí ẹbọ sísun tó wà lórí igi lórí iná;+ ọrẹ àfinásun tó ní òórùn dídùn* ló jẹ́ sí Jèhófà.+  “‘Tó bá jẹ́ látinú agbo ẹran ló ti fẹ́ mú ọrẹ wá fún Jèhófà láti fi rú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó jẹ́ akọ tàbí abo tí ara rẹ̀ dá ṣáṣá.+  Tó bá jẹ́ ọmọ àgbò ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà.  Kó gbé ọwọ́ lé orí ẹran tó mú wá, kí wọ́n sì pa á níwájú àgọ́ ìpàdé. Kí àwọn ọmọ Áárónì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ.  Kó mú ọ̀rá látinú ẹbọ ìrẹ́pọ̀, kó fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà.+ Kó gé ìrù rẹ̀ tó lọ́ràá nítòsí eegun ẹ̀yìn kúrò lódindi, ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká, 10  pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín+ náà. 11  Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ,* ọrẹ àfinásun sí Jèhófà+ ló jẹ́. 12  “‘Tó bá jẹ́ ewúrẹ́ ló fẹ́ fi ṣe ọrẹ, kó mú un wá síwájú Jèhófà. 13  Kó gbé ọwọ́ lé e lórí, kí wọ́n pa á níwájú àgọ́ ìpàdé, kí àwọn ọmọ Áárónì sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ sí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ. 14  Ibi tó máa fi ṣe ọrẹ àfinásun sí Jèhófà lára ẹran náà ni ọ̀rá tó bo ìfun, gbogbo ọ̀rá tó yí ìfun ká,+ 15  pẹ̀lú kíndìnrín méjèèjì àti ọ̀rá tó wà lára wọn nítòsí abẹ́nú. Kó tún yọ àmọ́ tó wà lára ẹ̀dọ̀ pẹ̀lú àwọn kíndìnrín rẹ̀. 16  Kí àlùfáà mú kó rú èéfín lórí pẹpẹ bí oúnjẹ, ọrẹ àfinásun tó máa mú òórùn dídùn* jáde ló jẹ́. Ti Jèhófà ni gbogbo ọ̀rá.+ 17  “‘Ó jẹ́ àṣẹ tó máa wà fún àwọn ìran yín títí lọ, ní gbogbo ibi tí ẹ̀ ń gbé: Ẹ ò gbọ́dọ̀ jẹ ọ̀rá tàbí ẹ̀jẹ̀+ èyíkéyìí.’”

Àlàyé Ìsàlẹ̀ Ìwé

Tàbí “ẹbọ àlàáfíà.”
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”
Ní Héb., “búrẹ́dì,” ìyẹn, ìpín ti Ọlọ́run nínú ẹbọ ìrẹ́pọ̀ náà.
Tàbí “tó tuni lójú.” Ní Héb., “atura.”