Àkóbá Wo Ni Ẹ̀rọ Ìgbàlódé Lè Ṣe fún Ìwọ Àtàwọn Ọ̀rẹ́ Ẹ?
Ẹ̀rọ ìgbàlódé wúlò púpọ̀. Àwọn èèyàn máa ń fi tẹ àtẹ̀jíṣẹ́ síra wọn, wọ́n fi ń kọ lẹ́tà, wọ́n lè lo ìkànnì àjọlò, wọ́n tiẹ̀ lè máa rí ara wọn bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀, ì báà tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀nà wọn jìn síra.
Àmọ́, àwọn kan ti sọ ọ̀rẹ́ wọn di ọ̀rẹ́ orí ẹ̀rọ ìgbàlódé, ohun tó sì máa ń ṣẹlẹ̀ sí wọn ni pé . . .
-
wọn kì í fi bẹ́ẹ̀ gba tàwọn ọ̀rẹ́ wọn rò.
-
wọ́n sábà máa ń dá wà, wọn kì í sì í láyọ̀.
-
wọ́n máa ń ro tara wọn nìkan.
OHUN TÓ YẸ KÓ O MỌ̀
ÌGBATẸNIRÒ
Tẹ́nì kan bá fẹ́ máa gba ti ọmọnìkejì ẹ̀ rò, àfi kó fara balẹ̀, kó sì fi sùúrù ronú nípa onítọ̀hún. Àmọ́ èèyàn ò lè ráyè ṣèyẹn níbi tó ti ń fọ̀rọ̀ ránṣẹ́, tó ń gba èsì pa dà, tó sì tún ń wo ohun tó ń lọ lórí ìkànnì àjọlò.
Tó o bá ń lo àkókò tó pọ̀ jù nídìí ẹ̀rọ ìgbàlódé, kó o tó mọ̀, gbogbo àkókò ẹ ni wàá máa fi fèsì àwọn ọrọ̀ tó ń wọlé látọ̀dọ̀ àwọn ọ̀rẹ́ ẹ. Ohun táá wá jẹ ẹ́ lógún ni bó o ṣe máa ráyè fèsì àwọn ọ̀rọ̀ náà dípò kó o wá bí wàá ṣe ran ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro lọ́wọ́.
RÒ Ó WÒ NÁ: Báwo lo ṣe máa bá àwọn òrẹ́ ẹ “kẹ́dùn” tó bá jẹ́ pé àtẹ̀jíṣẹ́ lo fi ń bá wọn sọ̀rọ̀?—1 PÉTÉRÙ 3:8.
ÌBÀNÚJẸ́
Ìwádìí kan fi hàn pé inú ọ̀pọ̀ èèyàn kì í dùn tí wọ́n bá ti pẹ́ jù lórí ìkànnì àjọlò; àti pé téèyàn bá kàn ṣáà ń wo fọ́tò àtàwọn nǹkan míì táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì, “á máa ṣèèyàn bíi pé ó kàn ń fàkókò ẹ̀ ṣòfò ni.”
Bákan náà, tẹ́nì kan bá ń wo àwọn fọ́tò tó jojú ní gbèsè táwọn kan gbé sórí ìkànnì àjọlò, inú ẹ̀ lè bà jẹ́ kó sì máa ronú pé ńṣe lòun ń jìyà níbi táwọn tó kù ti ń gbádùn ara wọn.
RÒ Ó WÒ NÁ: Tó o bá ń lo ìkànnì àjọlò, kí lo lè ṣe kó o má bàa fi ara ẹ wé àwọn èèyàn kan débi tí wàá fi ro ara ẹ pin?—GÁLÁTÍÀ 6:4.
ÌMỌTARA-ẸNI-NÌKAN
Olùkọ́ kan kíyè sí pé àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ẹ̀ kan máa ń ṣohun tó fi hàn pé “àwọn tí wọ́n bá lè rí jẹ lọ́dọ̀ wọn nìkan ni wọ́n máa ń bá ṣọ̀rẹ́.” * Ńṣe làwọn tó bá nírú ìwà yìí máa ń wo àwọn ọ̀rẹ́ wọn bíi fóònù téèyàn ń tẹ̀ nígbà tó bá nílò ẹ̀, táá sì pa á tì síbì kan nígbà tí kò bá nílò ẹ̀.
RÒ Ó WÒ NÁ: Ṣé ohun tó ò ń gbé sórí ìkànnì ò fi hàn pé kárími lò ń ṣe, tàbí pé ò ń fi ohun tó o ní ṣe fọ́rífọ́rí? —GÁLÁTÍÀ 5:26.
OHUN TÓ O LÈ ṢE
MÁA FỌGBỌ́N LO Ẹ̀RỌ ÌGBÀLÓDÉ
Tó o bá ń fọgbọ́n lo ẹ̀rọ ìgbàlódé, wàá máa ráyè fáwọn ọ̀rẹ́ ẹ, ọ̀rẹ́ yín á sì túbọ̀ máa lágbára.
ÌLÀNÀ BÍBÉLÌ: “Ìfẹ́ . . . kì í wá ire tirẹ̀ nìkan.”—1 KỌ́RÍŃTÌ 13:4, 5.
Sàmì sí àwọn tí wàá fẹ́ tẹ̀ lé lára àwọn àbá yìí tàbí kó o kọ èyí tíwọ fúnra ẹ ronú kàn.
-
Túbọ̀ máa bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀ lójúkojú (dípò kó o máa lo àtẹ̀jíṣẹ́ tàbí lẹ́tà orí ẹ̀rọ nìkan)
-
Wá ibì kan fi fóònù ẹ sí (tàbí kó o yí i sílẹ̀) tó o bá ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀
-
Dín àkókò tó o fi ń wo ohun táwọn èèyàn gbé sórí ìkànnì àjọlò kù
-
Túbọ̀ máa tẹ́tí sílẹ̀ táwọn èèyàn bá ń bá ẹ sọ̀rọ̀
-
Lọ sọ́dọ̀ ọ̀rẹ́ ẹ kan tó níṣòro kó o lè ràn án lọ́wọ́
^ ìpínrọ̀ 17 Ìwé Reclaiming Conversation ló sọ ọ́.