Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

ABALA 1

Ìmọ́lẹ̀ Tòótọ́ fún Aráyé

Ìmọ́lẹ̀ Tòótọ́ fún Aráyé

Ọ̀rọ̀ náà wà pẹ̀lú Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀, ó sì jẹ́ ọlọ́run kan (gnj 1 00:00–00:43)

Ipasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà ni Ọlọ́run dá gbogbo ohun mìíràn (gnj 1 00:44–01:00)

Ìyè àti ìmọ́lẹ̀ wà nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ náà (gnj 1 01:01–02:11)

Òkùnkùn ò borí ìmọ́lẹ̀ náà (gnj 1 02:12–03:59)

Lúùkù sọ ìdí tó fi kọ ìwé Ìhìn Rere tó kọ àti bó ṣe kọ ọ́, ó ń bá Tìófílọ́sì sọ̀rọ̀ (gnj 1 04:13–06:02)

Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jòhánù Arinibọmi (gnj 1 06:04–13:53)

Gébúrẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ pé wọ́n máa bí Jésù (gnj 1 13:52–18:26)

Màríà lọ kí mọ̀lẹ́bí ẹ̀ tó ń jẹ́ Èlísábẹ́tì (gnj 1 18:27–21:15)

Màríà gbé Jèhófà ga (gnj 1 21:14–24:00)

Bí wọ́n ṣe bí Jòhánù àti bí wọ́n ṣe sọ ọ́ lórúkọ (gnj 1 24:01–27:17)

Àsọtẹ́lẹ̀ tí Sekaráyà sọ (gnj 1 27:15–30:56)

Màríà lóyún nípasẹ̀ ẹ̀mí mímọ́; bó ṣe rí lára Jósẹ́fù (gnj 1 30:58–35:29)

Jósẹ́fù àti Màríà rìnrìn àjò lọ sí Bẹ́tílẹ́hẹ́mù; wọ́n bí Jésù (gnj 1 35:30–39:53)

Àwọn áńgẹ́lì fara han àwọn olùṣọ́ àgùntàn ní pápá (gnj 1 39:54–41:40)

Àwọn olùṣọ́ àgùntàn lọ sí ibùjẹ ẹran (gnj 1 41:41–43:53)

Wọ́n gbé Jésù wá sí tẹ́ńpìlì kí wọ́n lè fún Jèhófà (gnj 1 43:56–45:02)

Síméónì láǹfààní láti rí Kristi (gnj 1 45:04–48:50)

Ánà sọ̀rọ̀ nípa ọmọ náà (gnj 1 48:52–50:21)

Àwọn awòràwọ̀ wá kí Jésù, Hẹ́rọ́dù sì gbìyànjú láti pa á (gnj 1 50:25–55:52)

Jósẹ́fù mú Màríà àti Jésù, wọ́n sì sá lọ sí Íjíbítì (gnj 1 55:53–57:34)

Hẹ́rọ́dù pa àwọn ọmọkùnrin ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù àti ní gbogbo agbègbè rẹ̀ (gnj 1 57:35–59:32)

Jésù àtàwọn òbí ẹ̀ lọ ń gbé ìlú Násárẹ́tì(gnj 1 59:34–1:03:55)

Ohun tó ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jésù lọ sí tẹ́ńpìlì lọ́mọ ọdún méjìlá (12) (gnj 1 1:04:00–1:09:40)

Jésù àtàwọn òbí ẹ̀ pa dà sí Násárẹ́tì (gnj 1 1:09:41–1:10:27)

Ìmọ́lẹ̀ tòótọ́ máa tó wá sí ayé (gnj 1 1:10:28–1:10:55)