Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 17

Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

Báwo Ni Àwọn Alábòójútó Àyíká Ṣe Ń Ràn Wá Lọ́wọ́?

Orílẹ̀-èdè Màláwì

Àwùjọ àwọn tó fẹ́ lọ wàásù

Wọ́n wà lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù

Ìpàdé àwọn alàgbà

Ọ̀pọ̀ ìgbà ni Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì sọ̀rọ̀ nípa Bánábà àti àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọkùnrin yìí jẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, wọ́n sì ń bẹ àwọn ìjọ wò nígbà yẹn. Kí nìdí? Ìdí ni pé ọ̀rọ̀ àwọn ará tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run jẹ wọ́n lógún gan-an. Pọ́ọ̀lù sọ pé òun fẹ́ “pa dà lọ bẹ àwọn ará wò” kí òun lè rí bí wọ́n ṣe ń ṣe sí. Ó múra tán láti rin ìrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà kó lè lọ fún wọn ní ìṣírí. (Ìṣe 15:36) Ohun kan náà tí àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò wa ń ṣe lónìí nìyẹn.

Wọ́n ń bẹ̀ wá wò kí wọ́n lè fún wa níṣìírí. Alábòójútó àyíká máa ń bẹ nǹkan bí ogún (20) ìjọ wò, ó sì máa ń lo ọ̀sẹ̀ kan ní ìjọ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ la lè rí kọ́ látinú ìrírí àwọn arákùnrin yìí àti ti ìyàwó wọn, tí wọ́n bá ní ìyàwó. Wọ́n máa ń sapá láti mọ tèwe tàgbà, a jọ máa ń lọ wàásù, a sì jọ máa ń lọ sọ́dọ̀ àwọn tí à ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwọn alábòójútó yìí àtàwọn alàgbà jọ máa ń ṣe ìbẹ̀wò olùṣọ́ àgùntàn, wọ́n sì máa ń sọ àwọn àsọyé tó ń gbéni ró láwọn ìpàdé àtàwọn àpéjọ wa.​—Ìṣe 15:35.

Wọ́n ń fìfẹ́ hàn sí gbogbo èèyàn. Àwọn alábòójútó àyíká máa ń wá bí ìjọ ṣe máa tẹ̀ síwájú nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Wọ́n máa ń ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn alàgbà àti àwọn ìránṣẹ́ iṣẹ́ òjíṣẹ́ láti ṣàyẹ̀wò bí ìjọ ṣe ń ṣe dáadáa sí, wọ́n sì máa ń fún wọn ní ìmọ̀ràn tó wúlò lórí bí wọ́n ṣe lè bójú tó iṣẹ́ wọn. Wọ́n máa ń ran àwọn aṣáájú-ọ̀nà lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn láṣeyọrí, wọ́n tún máa ń fẹ́ mọ àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wá sípàdé àti bí wọ́n ṣe ń tẹ̀ síwájú sí nínú ìjọsìn Ọlọ́run. Ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn arákùnrin yìí ló ń yọ̀ǹda ara wọn tinútinú, “a sì jọ ń ṣiṣẹ́ fún ire [wa].” (2 Kọ́ríńtì 8:23) Ó yẹ ká máa tẹ̀ lé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ àti ìfọkànsin wọn sí Ọlọ́run.​—Hébérù 13:7.

  • Kí nìdí tí àwọn alábòójútó àyíká fi máa ń bẹ àwọn ìjọ wò?

  • Kí lo lè ṣe láti jàǹfààní látinú ìbẹ̀wò wọn?