Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 8

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?

Kí Nìdí Tá A Fi Ń Múra Dáadáa Nígbà Tá A Bá Ń Lọ sí Àwọn Ìpàdé Wa?

Orílẹ̀-èdè Iceland

Orílẹ̀-èdè Mẹ́síkò

Orílẹ̀-èdè Guinea-Bissau

Orílẹ̀-èdè Philippines

Ǹjẹ́ o kíyè sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nínú àwòrán inú ìwé yìí bí wọ́n ṣe múra dáadáa nígbà tí wọ́n ń lọ sí àwọn ìpàdé ìjọ? Kí nìdí tí a fi máa ń rí i pé aṣọ àti ìmúra wa bójú mu?

Ká lè bọ̀wọ̀ fún Ọlọ́run wa. Òótọ́ ni pé ìrísí wa nìkan kọ́ ni Ọlọ́run ń wò, ó tún má ń wo inú ọkàn wa. (1 Sámúẹ́lì 16:7) Nígbà tí a bá pé jọ láti sin Ọlọ́run, ohun tá a fẹ́ látọkàn wá ni pé ká bọ̀wọ̀ fún un àti fún àwọn tá a jọ ń sìn ín. Tá a bá fẹ́ lọ síwájú ọba tàbí ààrẹ orílẹ̀-èdè, a máa múra dáadáa torí pé èèyàn pàtàkì ni wọ́n. Bákan náà, bí a ṣe múra wá sí ìpàdé ń fi hàn pé a bọ̀wọ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run, “Ọba ayérayé” àti fún ibi tá a ti ń jọ́sìn rẹ̀.​—1 Tímótì 1:17.

Ká lè fi ìlànà tí à ń tẹ̀ lé hàn. Bíbélì rọ àwa Kristẹni pé ká máa múra lọ́nà tó fi “ìmọ̀wọ̀n ara ẹni àti àròjinlẹ̀” hàn. (1 Tímótì 2:9, 10) Ìmúra tó fi “ìmọ̀wọ̀n ara ẹni” hàn túmọ̀ sí pé ká má ṣe wọ aṣọ tó máa mú káwọn èèyàn máa wò wá, ìyẹn kéèyàn máa wọṣọ torí kó lè ṣe fọ́rífọ́rí, aṣọ tó ń mọ́kàn ẹni fà sí ìṣekúṣe tàbí èyí tó ṣí ara sílẹ̀. Bákan náà, “àròjinlẹ̀” ń jẹ́ ká yan aṣọ tó dáa, ká sì yẹra fún wíwọ aṣọ jákujàku tàbí ṣíṣe àṣejù nínú ìmúra wa. Ìlànà yìí fún wa láyè kí kálukú wọ aṣọ tó wù ú tó bá ṣáà ti dáa. Bí a ò tiẹ̀ sọ̀rọ̀, tí ìmúra wa bá bójú mu tó sì buyì kún wa, ó máa ‘ṣe ẹ̀kọ́ Olùgbàlà wa lọ́ṣọ̀ọ́,’ á sì “yin Ọlọ́run lógo.” (Títù 2:10; 1 Pétérù 2:12) Tá a bá múra dáadáa lọ sí àwọn ìpàdé wa, ó máa mú káwọn èèyàn fojú tó dáa wo ìjọsìn Jèhófà.

Má ṣe kọ ìpàdé sílẹ̀ torí pé o kò ní irú aṣọ kan tó o máa wọ̀ wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Kò dìgbà tí aṣọ wa bá jẹ́ olówó ńlá tàbí tó rí rèǹtè-rente kó tó jẹ́ aṣọ tó dáa, tó mọ́ tónítóní, tó sì bójú mu.

  • Kí nìdí tí ìmúra wa fi ṣe pàtàkì nígbà tá a bá ń jọ́sìn Ọlọ́run?

  • Àwọn ìlànà wo la máa ń tẹ̀ lé lórí ọ̀rọ̀ aṣọ àti ìmúra?