Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 9

Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?

Ọ̀nà Wo Ló Dáa Jù Láti Gbà Múra Ìpàdé Ìjọ Sílẹ̀?

Orílẹ̀-èdè Kàǹbódíà

Orílẹ̀-èdè Ukraine

Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó ṣeé ṣe kó o máa múra ibi tẹ́ ẹ máa kẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ kẹ́ ẹ tó ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Bákan náà, ó dára kó o máa múra ìpàdé ìjọ sílẹ̀ kó o tó lọ, kó o lè jàǹfààní tó pọ̀ gan-an. Téèyàn bá ń ṣe bẹ́ẹ̀ déédéé, ẹ̀kọ́ púpọ̀ lá máa rí kọ́.

Pinnu ìgbà tó o máa múra ìpàdé àti ibi tó o ti máa múra. Ìgbà wo ló rọrùn fún ẹ jù láti pọkàn pọ̀? Ṣé àárọ̀ kùtù ni, kó o tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́, àbí lálẹ́ nígbà tí àwọn ọmọ rẹ ti lọ sùn? Ká tiẹ̀ sọ pé o ò lè fi àkókò gígùn kẹ́kọ̀ọ́, yan iye àkókò tó o lè lò, kó o sì rí i dájú pé ohunkóhun ò dí ẹ lọ́wọ́. Wá ibi tí kò sí ariwo, kó o sì yẹra fún gbogbo ohun tó lè gbà ẹ́ lọ́kàn, pa rédíò, tẹlifíṣọ̀n àti fóònù rẹ. Máa gbàdúrà kó o tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, á jẹ́ kó o lè kó àníyàn ọjọ́ yẹn kúrò lọ́kàn kó o sì pọkàn pọ̀ sórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.​—Fílípì 4:6, 7.

Sàmì sí àwọn kókó inú ibi tí a fẹ́ kọ́, kó o sì múra láti dá sí i. Kọ́kọ́ wo àwọn kókó tó wà nínú ibi tá a fẹ́ kọ́. Ronú nípa àkòrí àpilẹ̀kọ tàbí orí ìwé náà, kó o sì wo bí ìsọ̀rí kọ̀ọ̀kan ṣe tan mọ́ kókó pàtàkì inú àpilẹ̀kọ náà, wo àwọn àwòrán tó wà níbẹ̀, kó o sì ka àwọn ìbéèrè tó gbé àwọn kókó inú ẹ̀kọ́ náà yọ. Lẹ́yìn náà, ka ìpínrọ̀ kọ̀ọ̀kan, kó o sì wá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè tó wà níbẹ̀. Ṣí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà níbẹ̀, kà wọ́n, kó o sì ronú nípa bí wọ́n ṣe ti ọ̀rọ̀ náà lẹ́yìn. (Ìṣe 17:11) Tó o bá ti rí ìdáhùn, fa ìlà sí i tàbí kó o sàmì sí àwọn ọ̀rọ̀ pàtàkì tàbí àpólà ọ̀rọ̀ nínú ìpínrọ̀ náà, tó máa jẹ́ kó o rántí ìdáhùn náà. Ní ìpàdé, o lè nawọ́ nígbà tó o bá fẹ́, kó o sì dáhùn ṣókí ní ọ̀rọ̀ ara rẹ.

Bó o ṣe ń ka oríṣiríṣi ẹ̀kọ́ tá à ń jíròrò lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ nípàdé, wàá máa fi àwọn ohun tuntun kún ‘ibi tí ò ń kó ìṣúra sí,’ ìyẹn ìmọ̀ tó o ní nípa Bíbélì.​—Mátíù 13:51, 52.

  • Àwọn nǹkan wo lo lè máa ṣe láti múra àwọn ìpàdé sílẹ̀ déédéé?

  • Báwo lo ṣe lè múra sílẹ̀ láti dáhùn ní ìpàdé?