Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ̀KỌ́ 3

Báwo Ni A Ṣe Wá Mọ Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni?

Báwo Ni A Ṣe Wá Mọ Òtítọ́ Tí Bíbélì Fi Kọ́ni?

Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ọdún 1870 sí 1879

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tí wọ́n kọ́kọ́ tẹ̀ jáde, ọdún 1879

Ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ rèé lónìí

Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ pé lẹ́yìn tí Kristi bá kú, àwọn olùkọ́ èké máa dìde láàárín àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n á sì sọ òtítọ́ tí Bíbélì kọ́ni dìdàkudà. (Ìṣe 20:29, 30) Ohun tó ṣẹlẹ̀ gan-an nìyẹn nígbà tó yá. Wọ́n da ẹ̀kọ́ Jésù pọ̀ mọ́ ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn àwọn kèfèrí, ayédèrú ẹ̀sìn Kristẹni sì bẹ̀rẹ̀. (2 Tímótì 4:3, 4) Báwo ló ṣe dá wa lójú lóde òní pé a mọ ohun náà gan-an tí Bíbélì fi kọ́ni?

Àkókò tó lójú Jèhófà láti jẹ́ kí àwọn èèyàn mọ òtítọ́. Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé ‘ní àkókò òpin, ìmọ̀ tòótọ́ máa pọ̀ yanturu.’ (Dáníẹ́lì 12:4) Ní ọdún 1870, àwùjọ kékeré kan tó fẹ́ mọ òtítọ́ rí i pé ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ni kò bá Ìwé Mímọ́ mu. Torí náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í wá bí wọ́n ṣe máa lóye ohun náà gan-an tí Bíbélì fi kọni, Jèhófà sì mú kí wọ́n lóye Ìwé Mímọ́.

Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọ̀nà tí àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n ní ìtara, ìyẹn àwọn tó wà ṣáájú wa gbà kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni àwa náà ń gbà kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lónìí. Wọ́n máa ń ṣàlàyé ẹ̀kọ́ Bíbélì lọ́kọ̀ọ̀kan. Tí wọ́n bá rí apá kan nínú Bíbélì tó ṣòro láti lóye, wọ́n máa ń wá àwọn ẹsẹ míì tó lè ṣàlàyé rẹ̀ nínú Bíbélì. Tí wọ́n bá ti fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tó bá àwọn apá tó kù nínú Ìwé Mímọ́ mu, wọ́n á kọ ọ́ sílẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń jẹ́ kí Bíbélì ṣàlàyé ara rẹ̀ yìí ni wọ́n fi wá mọ ohun tó jẹ́ òtítọ́ nípa orúkọ Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀, ohun tó ní lọ́kàn fún aráyé àti ayé, ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí àwọn òkú àti ìrètí pé àwọn òkú máa jíǹde. Ìwádìí tí wọ́n ṣe yìí mú kí wọ́n bọ́ lọ́wọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ èké àtàwọn àṣà tínú Ọlọ́run kò dùn sí.​—Jòhánù 8:31, 32.

Nígbà tó di ọdún 1879 àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì rí i pé ó ti tó àkókò láti jẹ́ kí àwọn èèyàn níbi gbogbo mọ òtítọ́. Torí náà, lọ́dún yẹn wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í tẹ ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ jáde lédè Gẹ̀ẹ́sì, ìyẹn The Watchtower Announcing Jehovah’s Kingdom, a ṣì ń tẹ̀ ẹ́ jáde títí dòní. Ní báyìí, à ń sọ òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni fún àwọn èèyàn ní igba ó lé ogójì (240) orílẹ̀-èdè ní èdè tó lé ní ọgọ́rùn-ún méje àti àádọ́ta (750). Ìmọ̀ òtítọ́ kò tíì pọ̀ tó yìí rí!

  • Lẹ́yìn tí Kristi kú, kí ló ṣẹlẹ̀ sí òtítọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni?

  • Kí ló ràn wá lọ́wọ́ láti wá mọ òtítọ́ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi kọ́ni?