Irú Ìwé Wo Ni Bíbélì?
Ṣé o rò pé . . .
-
ìwé tí wọ́n fi ọgbọ́n èèyàn kọ ni?
-
àbí ìwé ìtàn àròsọ?
-
àbí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ
“Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí.”—2 Tímótì 3:16, Bíbélì Ìtumọ̀ Ayé Tuntun.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ O MÁA RÍ
Wàá rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè pàtàkì nípa ìgbésí ayé.—Òwe 2:1-5.
Wàá rí ìtọ́sọ́nà tó ṣeé gbára lé tó máa wúlò fún ẹ lójoojúmọ́.—Sáàmù 119:105.
Ó máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀la ń bọ̀ wá dáa.—Róòmù 15:4.
ṢÉ A LÈ GBA OHUN TÍ BÍBÉLÌ SỌ GBỌ́?
Bẹ́ẹ̀ ni. Mẹ́ta lára ìdí tó fi yẹ ká gba ọ̀rọ̀ Bíbélì gbọ́ rèé:
-
Ọ̀rọ̀ inú rẹ̀ bára mu látòkèdélẹ̀. Nǹkan bí ogójì (40) èèyàn ló kọ Bíbélì, ó sì tó ẹgbẹ̀rún kan ó lé ọgọ́rùn-ún mẹ́fà (1,600) ọdún tí wọ́n fi kọ ọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn kò rí ara wọn rí. Síbẹ̀ gbogbo ohun tó wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n kọ bára mu, ohun kan náà ló sì dá lé!
-
Òtítọ́ ni ìtàn inú rẹ̀. Lọ́pọ̀ ìgbà, àwọn tó máa ń kọ ìtàn nínú ayé kì í fẹ́ sọ àṣìṣe àwọn èèyàn wọn. Àmọ́ àwọn tó kọ Bíbélì kò fi ọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ nípa àṣìṣe tí wọ́n ṣe àtèyí táwọn èèyàn wọn ṣe.—2 Kíróníkà 36:15, 16; Sáàmù 51:1-4.
-
Àsọtẹ́lẹ̀ inú rẹ̀ ṣeé gbára lé. Bíbélì sọ tẹ́lẹ̀ nípa bí ìlú Bábílónì àtijọ́ ṣe máa pa run ní nǹkan bí igba (200) ọdún ṣáájú kó tó wáyé. (Àìsáyà 13:17-22) Yàtọ̀ sí pé ó sọ bí wọ́n ṣe máa pa ìlú náà run, ó tún sọ orúkọ ọ̀gá ológun tó máa pa á run!—Àìsáyà 45:1-3.
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àsọtẹ́lẹ̀ míì nínú Bíbélì ló tún ṣẹ láìkù síbì kan. Ṣebí ohun tá a retí pé kí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe náà nìyẹn?—2 Pétérù 1:21.
RÒ Ó WÒ NÁ
Báwo ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe lè mú kí ayé rẹ dára sí i?
Bíbélì dáhùn ìbéèrè yìí nínú ìwé ÀÌSÁYÀ 48:17, 18 àti 2 TÍMÓTÌ 3:16, 17.