Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

APÁ 1

‘Agbára Rẹ̀ Ń Bani Lẹ́rù’

‘Agbára Rẹ̀ Ń Bani Lẹ́rù’

Nínú apá yìí, a máa ṣàyẹ̀wò àwọn ìtàn Bíbélì tó fi hàn pé Jèhófà lágbára láti ṣẹ̀dá, láti pani run, láti dáàbò boni àti láti mú nǹkan bọ̀ sípò. Bá a bá ṣe ń rí i pé ‘agbára Jèhófà ń bani lẹ́rù’ àti pé “okun rẹ̀ tó fi ń ṣiṣẹ́ pọ̀ yanturu,” ìyẹn á jẹ́ ká nígboyà, ìrètí wa á sì dájú.​—Àìsáyà 40:26.

NÍ APÁ YÌÍ

ORÍ 4

‘Agbára Jèhófà Pọ̀’

Ṣó yẹ ká máa bẹ̀rù Ọlọ́run torí pé ó jẹ́ alágbára? A lè sọ pé bẹ́ẹ̀ ni, a sì tún lè sọ pé bẹ́ẹ̀ kọ́.

ORÍ 5

Agbára Ìṣẹ̀dá​—“Aṣẹ̀dá Ọ̀run àti Ayé”

Látorí oòrùn tó ń tú ibú agbára jáde dórí ẹyẹ akùnyùnmù kékeré, a lè kọ́ ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ nípa Jèhófà látara àwọn ohun tó dá.

ORÍ 6

Agbára Ìparun​—“Jagunjagun Tó Lágbára Ni Jèhófà”

Tó bá jẹ́ pé “Ọlọ́run àlàáfíà” ni Jèhófà lóòótọ́, kí nìdí tó fi ń jagun?

ORÍ 7

Agbára Ààbò​—“Ọlọ́run Ni Ibi Ààbò Wa”

Ọ̀nà méjì ni Ọlọ́run ń gbà dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, àmọ́ ọ̀nà kan ṣe pàtàkì ju ìkejì lọ.

ORÍ 8

Agbára Ìmúbọ̀sípò​—Jèhófà “Ń Sọ Ohun Gbogbo Di Tuntun”

Jèhófà ti mú ìjọsìn mímọ́ bọ̀ sípò. Àwọn nǹkan wo ló máa mú bò sípò lọ́jọ́ iwájú?

ORÍ 9

“Kristi Ni Agbára Ọlọ́run”

Kí làwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe àtàwọn ohun tó fi kọ́ni jẹ́ ká mọ̀ nípa Jèhófà?

ORÍ 10

“Ẹ Máa Fara Wé Ọlọ́run” Bẹ́ Ẹ Ṣe Ń Lo Agbára

Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti rí i pé ìwọ náà lágbára láti ṣe àwọn nǹkan kan. Báwo lo ṣe lè lo agbára tó o ní yìí lọ́nà tó dáa?