Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

FPG/The Image Bank via Getty Images

Ẹ MÁA ṢỌ́NÀ!

Àwọn Olóṣèlú Ń Kìlọ̀ Pé Ogun Amágẹ́dọ́nì Máa Tó Jà​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

Àwọn Olóṣèlú Ń Kìlọ̀ Pé Ogun Amágẹ́dọ́nì Máa Tó Jà​—Kí Ni Bíbélì Sọ?

 Láàárọ̀ ọjọ́ Monday, October 10, 2022, àwọn ọmọ ogun Rọ́ṣíà ju bọ́ǹbù sáwọn ìlú tó wà káàkiri orílẹ̀-èdè Ukraine. Ìdí ni pé lọ́jọ́ méjì ṣáájú ìgbà yẹn, bọ́ǹbù kan ba afárá tí wọ́n lè fi sọdá láti ìlú Crimea sí Rọ́ṣíà jẹ́. Ohun kan tó gbàfiyèsí ni pé kò pẹ́ táwọn olóṣèlú kìlọ̀ pé ogun Amágẹ́dọ́nì ò ní pẹ́ jà làwọn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí wáyé.

  •   “Látìgbà tí ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà ìyẹn John F. Kennedy àtàwọn ará Cuba ti fa wàhálà tó fẹ́rẹ̀ẹ́ dá ogun Amágẹ́dọ́nì sílẹ̀, àsìkò yìí ló tún ṣeé ṣe kí ogun yẹn wáyé. . . . Mi ò rò pé ó ṣeé ṣe fún ẹnikẹ́ni láti lo bọ́ǹbù átọ́míìkì kékeré, kíyẹn má sì fa ogun Amágẹ́dọ́nì.”​—Joe Biden tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, October 6, 2022.

  •   “Mo gbà pé kò sẹ́ni tí ogun Amágẹ́dọ́nì yìí ò ní kàn ní gbogbo ayé.”​—Volodymyr Zelensky tó jẹ́ ààrẹ orílẹ̀-èdè Ukraine ló sọ bẹ́ẹ̀ nígbà tí wọ́n bi í nípa ohun tó máa ṣẹlẹ̀ tẹ́nì kan bá lo bọ́ǹbù átọ́míìkì, BBC News, October 8, 2022.

 Ṣé lílo bọ́ǹbù átọ́míìkì ló máa fa ogun Amágẹ́dọ́nì? Kí ni Bíbélì sọ?

Ṣé lílo bọ́ǹbù átọ́míìkì ló máa fa ogun Amágẹ́dọ́nì?

 Rárá o. Inú Ìfihàn 16:16 nìkan ni ọ̀rọ̀ náà “Amágẹ́dọ́nì” ti fara hàn nínú Bíbélì. Ohun kan ni pé kì í ṣe ogun tó máa wáyé láàárín àwọn orílẹ̀-èdè lọ̀rọ̀ náà ń tọ́ka sí, bí kò ṣe ogun tó máa wáyé láàárín Ọlọ́run àti “àwọn ọba gbogbo ilẹ̀ ayé tí à ń gbé.” (Ìfihàn 16:14) Ogun Amágẹ́dọ́nì yìí ni Ọlọ́run máa lò láti fòpin sí ìjọba èèyàn.​—Dáníẹ́lì 2:44.

 Tó o bá fẹ́ mọ̀ bóyá ogun Amágẹ́dọ́nì máa pa ayé yìí run, ka àpilẹ̀kọ náà Kí Ni Ogun Amágẹ́dọ́nì?

Ṣé bọ́ǹbù átọ́míìkì máa pa ayé yìí àti gbogbo àwa tá à ń gbé inú ẹ̀ run?

 Rárá. Òótọ́ ni pé àwọn alákòóso ayé lè lo bọ́ǹbù átọ́míìkì lọ́jọ́ iwájú, Ọlọ́run ò ní jẹ́ kí ayé yìí pa run. Bíbélì sọ pé:

  •   “Ayé wà títí láé.”​—Oníwàásù 1:4.

  •   “Àwọn olódodo ni yóò jogún ayé, wọn yóò sì máa gbé inú rẹ̀ títí láé.”​—Sáàmù 37:29.

 Àmọ́, àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì àtàwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ báyìí jẹ́ kó hàn kedere pé nǹkan máa tó yí pa dà láìpẹ́. (Mátíù 24:3-7; 2 Tímótì 3:1-5) O lè mọ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọjọ́ ọ̀la tó o bá jẹ́ kí ẹnì kan wá kọ́ ẹ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́.