Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ayé Ò Ní Pẹ́ Pa Run? Kí Ni Àpókálíìsì?

Ṣé Ayé Ò Ní Pẹ́ Pa Run? Kí Ni Àpókálíìsì?

 Kí ló máa ń wá sí ẹ lọ́kàn tó o bá gbọ́ ọ̀rọ̀ náà “àpókálíìsì”? Ó lè mú kó o ronú nípa àjálù kan tó kárí ayé, tó ṣeé ṣe kó pa gbogbo ohun alààyè tó wà lórí ilẹ̀ ayé run. Àwọn kan gbà pé ayé máa tó kàgbákò irú àjálù bẹ́ẹ̀, pàápàá nígbà tí wọ́n bá ka àwọn ìròyìn bí irú èyí:

  •   “Ó ṣeé ṣe kí ogun táwọn orílẹ̀-èdè á ti máa ju bọ́ǹbù atọ́míìkì ńláńlá jà láìpẹ́, yálà láìròtẹ́lẹ̀, nítorí èdèkòyédè tàbí kó jẹ́ àfọwọ́fà.”—Bulletin of the Atomic Scientists.

  •   “Ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tó pabanbarì ti ṣẹlẹ̀ kárí ayé, irú bí ìjì ńláńlá, iná inú igbó, ọ̀dá, bíba iyùn táwọn ohun abẹ̀mí ń gbé inú rẹ̀ lábẹ́ omi jẹ́, ooru gbígbóná àti omíyalé.”—National Geographic.

  •   “Ó pẹ́ tí ọ̀wọ́ àwọn eéṣú ti ṣọṣẹ́ báyìí nílẹ̀ Áfíríkà.”—The Associated Press.

 Ṣé àjálù kan tó kárí ayé ló máa pa ayé wa yìí run? Kí ni Bíbélì sọ?

Ṣé ilẹ̀ ayé yìí máa pa rún?

 Rárá o. Bíbélì fi dá wa lójú pé ayé máa wà títí láé. (Oníwàásù 1:4) Dípò tí Ọlọ́run á fi pa ayé yìí run, àwọn “tó ń run ayé” ní òpin máa dé bá.—Ìṣípayá 11:18.

Ṣé ayé yìí máa pa run?

 Bíbélì sọ pé, “ayé” tí òpin máa dé bá ni àwọn èèyàn tí kò ka Ọlọ́run sí tí wọ́n sì ń ṣe ohun tó wù wọ́n. Bí Ọlọ́run ti ṣe nígbà ayé Nóá, “ayé àwọn tí kò ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run” ló máa fòpin sí.”—2 Pétérù 2:5; 3:7.

 1 Jòhánù 2:17 ṣe sọ, “ayé ń kọjá lọ àti ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ rẹ̀.” Ẹṣẹ Bíbélì yìí fi hàn pé kì í ṣe ilẹ̀ ayé wa ni Ọlọ́run máa pa run, bí kò ṣe àwọn èèyàn tí kò jáwọ́ nínú ìwà búburú.

Ìgbà wo ni òpin máa dé?

 Bíbélì ò sọ àkókò pàtó tí òpin máa dé fún wa. (Mátíù 24:36) Ṣùgbọ́n, ó jẹ́ ká mọ̀ pé òpin ti sún mọ́lé. Àwọn nǹkan tí Bíbélì sọ pé ó máa ṣẹlẹ̀ rèé:

  •   Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ bí ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn àti ìmìtìtì ilẹ̀ tó ń bani lẹ́rù á máa ṣẹlẹ̀ “láti ibì kan dé ibòmíì.”—Mátíù 24:3, 7, 14; Lúùkù 21:10, 11; Ìfihàn 6:1-8.

  •   Àwọn èèyàn á máa hùwà tó fi hàn ní gbogbo ọ̀nà pé tara wọn nìkan ni wọ́n mọ̀. Bí àpẹẹrẹ, wọ́n á di ẹni tó “nífẹ̀ẹ́ owó,” “aláìmoore,” àti “ẹni tí kò lè kó ara rẹ̀ níjàánu.”—2 Tímótì 3:1-5.

 Ọ̀pọ̀ èèyàn gbà pé láti ọdún 1914 ni àwọn nńkan tó ń ṣẹlẹ̀ nínú ayé ti rí bí Bíbélì ṣe sọ àti pé òpin ti sún mọ́lé. Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, wo àwọn àpilẹ̀kọ náà “Kí Ni Àwọn Ìtàn Inú Bíbélì Tó Tẹ̀ Léra Fi Hàn Nípa Ọdún 1914?” àti “Kí Ni Àmì ‘Àwọn Ọjọ́ Ìkẹyìn,’ Tàbí ‘Àkókò Òpin’?

Kí ni “àpókálíìsì” túmọ̀ sí nínú Bíbélì?

 Ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà “àpókálíìsì” túmọ̀ sí “ṣíṣí ìbòjú” tàbí “títú síta.” Lọ́pọ̀ ìgbà, ọ̀rọ̀ náà sábà máa ń túmọ̀ sí pé kéèyàn sọ ohun tó wà ní ìpamọ́ síta. Bíbélì tún sọ̀rọ̀ nípa “ìfihàn [ìyẹn ìṣípayá tàbí àpókálíìsì] Jésù Olúwa,” èyí tó wáyé nígbà tí Ọlọ́run jẹ́ kó hàn pé Jésù ni ẹni tó ní agbára láti mú gbogbo ìwà burúkú kúrò lórí ilẹ̀ ayé, kó sì san àwọn tó sin Ọlọ́run lẹ́san.—2 Tẹsalóníkà 1:6, 7; 1 Pétérù 1:7, 13.

 A·po·kaʹly·psis, tàbí Ìfihàn ni orúkọ ìwé tó gbẹ̀yìn nínú Bíbélì, torí pé ó sọ àwọn ohun tó ń bọ̀ wá ṣẹlẹ̀ lọ́jọ́ iwájú fún wa. (Ìfihàn 1:1) Ọ̀rọ̀ tó ń fini lọ́kàn balẹ̀ tó sì ń fúnni nírètí ló wà nínú ìwé náà. (Ìfihàn 1:3) Ìwé yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run máa mú gbogbo ìwà burúkú kúrò, ó sì máa sọ ayé di Párádísè. Nígbà yẹn, àwọn èèyàn ò ní kú mọ́, kò sì ní sí ìyà àti ìrora mọ́.—Ìfihàn 21:3, 4.

 Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa àwọn ìlérí àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe yìí? Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́fẹ̀ẹ́, wọ́n sì lè ràn ẹ́ lọ́wọ́. A rọ̀ ẹ́ pé kó o kàn sí wọ́n kẹ́ ẹ lè jọ máa kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.