Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

MAY 26, 2017
RỌ́ṢÍÀ

Àwọn Ọlọ́pàá Ya Wọ Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Rọ́ṣíà, Wọ́n Mú Ọmọ Ilẹ̀ Denmark Kan Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Wọ́n sì Fi Sẹ́wọ̀n

Àwọn Ọlọ́pàá Ya Wọ Ìpàdé Àwọn Ẹlẹ́rìí ní Rọ́ṣíà, Wọ́n Mú Ọmọ Ilẹ̀ Denmark Kan Tó Jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà, Wọ́n sì Fi Sẹ́wọ̀n

NEW YORK—Lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà dá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́bi ní April 20, 2017, àwọn ọlọ́pàá ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nírọ̀lẹ́ May 25, 2017, wọ́n sì mú ọmọ ilẹ̀ Denmark kan àtàwọn míì tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà.

Dennis Christensen

Ó kéré tán, àwọn ọlọ́pàá àtàwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] tó dira ogun ló ya wọ ibi táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn ní ìrọwọ́rọsẹ̀ nílùú Oryol (tí wọ́n tún ń pè ní Orel), tí àwòrán rẹ̀ wà lókè yìí. Àwọn ọlọ́pàá gba ẹ̀dà ìwé ìdánimọ̀ gbogbo àwọn tó wà nípàdé náà, wọ́n sì gba àwọn fóònù àti tablet wọn. Àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba tún mú Dennis Christensen, ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó jẹ́ ọmọ ilẹ̀ Denmark. Kò pẹ́ lẹ́yìn ìyẹn tí àwọn ọlọ́pàá lọ tú ilé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà mẹ́rin nílùú náà.

Lẹ́yìn tí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò Ìjọba fi Ọ̀gbẹ́ni Christensen sí àhámọ́ di ọjọ́ kejì lọ́gbà wọn, Ilé Ẹjọ́ Soviet District Court nílùú Oryol fọwọ́ sí ìwé táwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò kọ sí wọn, wọ́n sì pàṣẹ pé kí wọ́n fi ọkùnrin náà sí àtìmọ́lé kí àwọn Ẹ̀ṣọ́ Aláàbò tó parí ìwádìí tí wọ́n ń ṣe, tí ilé ẹjọ́ á sì wá gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀. Látìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti dá ẹjọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn, Ọ̀gbẹ́ni Christensen lẹni àkọ́kọ́ tó jẹ́ ọmọ orílẹ̀-èdè míì táwọn aláṣẹ máa mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ wọnú àtakò tí wọ́n ń ṣe sáwọn Ẹlẹ́rìí ní Rọ́ṣíà. Tí ilé ẹjọ́ bá sọ pé ó jẹ̀bi, ó ṣeé ṣe kó fi ẹ̀wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ gbára.

Àtìgbà tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà ti sọ pé agbawèrèmẹ́sìn làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó sì ti fòfin de Ẹ̀ka Ọ́fíìsì wọn àti ibi márùn-dín-nírínwó [395] tí wọ́n ti forúkọ ẹ̀sìn wọn sílẹ̀ káàkiri orílẹ̀-èdè náà ni àwọn aláṣẹ àtàwọn míì ti bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú hùwà ipá sáwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó lé ní ogójì [40] irú ẹ̀ tó ti ṣẹlẹ̀, èyí tó sì ṣẹlẹ̀ nílùú Oryol yìí ló wáyé gbẹ̀yìn.

Àwọn jàǹdùkú dáná sun ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn.

Kò tíì ju wákàtí mélòó kan lẹ́yìn tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ṣèdájọ́ ní April 20, tí àwọn ọkùnrin kan nílùú St. Petersburg lọ ba ibi tó tóbi jù táwọn Ẹlẹ́rìí ti ń jọ́sìn ní Rọ́ṣíà jẹ́, wọ́n tiẹ̀ tún halẹ̀ mọ́ àwọn tó ń jọ́sìn níbẹ̀. Àwọn jàǹdùkú yìí tún ti lọ ṣọṣẹ́ láwọn ibòmíì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń jọ́sìn, títí kan àwọn ilé tí wọ́n ń gbé nílùú Kaliningrad, Moscow, Penza, Rostov, St. Petersburg, Sverdlovsk, Voronezh àti Krasnoyarsk. Irú ẹ̀ kan ṣẹlẹ̀ ní May 24, 2017, nílùú Zheshart ní Komi Republic. Àwọn jàǹdùkú lọ dáná sun ilé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń pàdé. Yàtọ̀ sí báwọn ọlọ́pàá ṣe ń ya wọ ilé àwọn Ẹlẹ́rìí, táwọn jàǹdùkú sì ń yọ wọ́n lẹ́nu, wọ́n máa ń gbéjà ko Ẹlẹ́rìí Jèhófà kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń halẹ̀ mọ́ wọn níbi iṣẹ́ àti níléèwé, iṣẹ́ sì ń bọ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí yìí.

David A. Semonian, tó jẹ́ agbẹnusọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní oríléeṣẹ́ wọn sọ pé: “Ọ̀rọ̀ àwọn ará wa ní Rọ́ṣíà túbọ̀ ń ká àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kárí ayé lára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Ó ṣe kedere pé ẹjọ́ tí kò tọ́ tí Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Rọ́ṣíà dá lórí ọ̀rọ̀ wa ló bí gbogbo ohun tójú wa ń rí yìí. A ti kọ̀wé pe ẹjọ́ kòtẹ́milọ́rùn lórí ọ̀rọ̀ náà ní May 19, 2017. Èyí á jẹ́ kí àǹfààní míì yọjú fún ìjọba orílẹ̀-èdè Rọ́ṣíà láti fòpin sí ìwàkiwà táwọn èèyàn ń hù sí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtohun tí kò lẹ́sẹ̀ ńlẹ̀ tí wọ́n ń fojú wa rí. A tún máa kọ̀wé sí àwọn aláṣẹ lórí ọ̀rọ̀ Dennis Christensen, ọ̀kan lára àwọn ará wa tí wọ́n tì mọ́lé láìtọ́.”

Agbẹnusọ fún Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà:

Kárí Ayé: David A. Semonian, Ọ́fíìsì Agbéròyìnjáde, +1-845-524-3000