Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

AUGUST 16, 2019
DENMARK

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣí Ibi Tuntun Tí Wọ́n Kó Onírúurú Bíbélì Sí Lórílẹ̀-Èdè Denmark

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Ṣí Ibi Tuntun Tí Wọ́n Kó Onírúurú Bíbélì Sí Lórílẹ̀-Èdè Denmark

Ní July 2019, a ṣí ibi tuntun tí wọ́n kó onírúurú Bíbélì sí ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Scandinavia, nílùú Holbæk lórílẹ̀-èdè Denmark, ibẹ̀ ò jú nǹkan bi kìlómítà márùndínláàádọ́rin (65) sí ìlú Copenhagen. Àkòrí tí wọ́n kọ síbi tí wọ́n kó àwọn Bíbélì náà sí ni “The Bible and the Divine Name in Scandinavia” tó túmọ̀ sí Bíbélì àti Orúkọ Àtọ̀runwá Náà ní Scandinavia.

Níbẹ̀, wàá rí àtẹ kan tí wọ́n kó ọ̀pọ̀ Bíbélì tó ṣàrà ọ̀tọ̀ sí lédè Danish, Faeroese, Greenlandic, Icelandic, Norwegian, Saami àti Swedish. Bíbélì tó wà nínú àtẹ yìí ju àádọ́ta (50) lọ.

Ọ̀kan lára ohun tó ṣe pàtàkì jù nínú àtẹ náà ni Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ Gustav Vasa ti ọdún 1541. Òun ni odindi Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lédè Scandinavia. Inú Bíbélì Gustav Vasa ni wọ́n ti mú èyí tó pọ̀ jù nínú gírámà àti ọ̀rọ̀ èdè àwọn ará Sweden. Wọ́n tún lò ó láti fi túmọ̀ àwọn Bíbélì míì lédè Sweden fún ọgọ́rùn-ún mẹ́ta (300) ọdún tó tẹ̀ lé e.

Wọ́n pàtẹ Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ Gustav Vasa ti ọdún 1541 síbi tí wọ́n ń kó nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé sí

Ohun tó tún ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú àtẹ náà ni Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ 1550 Christian III ti ọdún 1550. Òun ni odindi Bíbélì àkọ́kọ́ tí wọ́n ṣe lédè Danish. Ìlànà tí wọ́n fi kọ Bíbélì Christian III ni wọ́n lò nínú èdè Danish, kódà ọ̀rọ̀ inú ẹ̀ ti di ara èdè tí ọ̀pọ̀ lára àwọn ará Àríwá Yúróòpù ń lò báyìí.

Ẹ̀dà Bíbélì ìpilẹ̀ṣẹ̀ Christian III ti ọdún 1550

Erik Jørgensen tó wà ní ẹ̀ka ọ́fíìsì orílẹ̀-èdè Scandinavia sọ pé: “Ibi tuntun tí wọ́n ń kó onírúurú Bíbélì sí yìí ti jẹ́ ka rí i pé láti ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn làwọn ará Scandinavia ti ní ìfẹ́ tó jinlẹ̀ fún Ọrọ̀ Ọlọ́run àti orúkọ rẹ̀ tí kò lẹ́gbẹ́, ìyẹn Jèhófà.”