ẸKỌ 04
Nesin Re Ṣe Oriṣẹ Ọrọnfọ?
Kuri ira ti irẹye gba te winọrọn kọkọ, owun a gba winọrọn sẹn oriṣẹ eju ikẹnẹkun toro gidijẹ. Dẹreke, Baibol fọ ni ubara Oriṣẹ ọkan ti o ‘laju oriṣẹ mirẹn dede.’ (2 Kronikol 2:5) Ẹrẹn nesin? Kẹnrẹn, nikọ re lẹghẹ ẹ laju aghan oriṣẹ mirẹn dede ti irẹye ka sẹn? Ni ẹkọ eyiwe, wo wa kọ biri Oriṣẹ we te wewe ara ro gbẹ rẹ.
1. Nikọ re ṣe ọrukọ Oriṣẹ ọrọnfọ, kẹnrẹn bokọ ẹnẹ te man gin o fẹ di ẹnẹ maan?
Ni inọ Baibol, Oriṣẹ wewe ara ro gbẹ ẹnẹ wawe. O gin: “Emi re ṣe Jihova. Ẹrẹn re ṣe ọrukọ mi.” (Aisaya 42:8, nwt) “Jihova” re ṣe biri a te yi ọrukọ Ibru ọkan dẹ, ti ọmiwe gidijẹ gin alẹ ro jẹ “O nemi ṣe urun-ki-urun.”[2] Jihova fẹ di ẹnẹ man ọrukọ ro. (Ẹksọdọs 3:15) Bokọ ẹnẹ te man wẹrẹ? Baibol lo ọrukọ we ti o ju ugba 7,000![3] a Ọrukọ we, Jihova, re ṣe ọrukọ “Oriṣẹ ti o ṣe ọrọnfọ” ni ọrọn biri alẹ ẹye.—1 Jọn 5:20.
2. Nikọ wun Baibol gin gbẹ ẹnẹ ni ubara Jihova?
Baibol gin gbẹ ẹnẹ gin, ni ẹbu oriṣẹ ti irẹye ka sẹn dede, Jihova nọkan re ṣe Oriṣẹ ọrọnfọ. Teri nikọ? Teri urun gidijẹ rẹẹn. Jihova re nẹ aṣẹ ti o laju fẹnẹfẹnẹ, teri ẹrẹn owun re ṣe “Ọnẹ ti o Laju ni ẹye dede.” (Sam 83:18, nwt) Owun re ṣe “Ọlinini Dede,” ti o jẹ gin o nẹ agbara gba ṣe urun-ki-urun ti won ma fẹ ṣe. Owun “re da urun-ki-urun dede”—ọrọn biri alẹ ẹye, biri urun ti o wi alẹ ẹye dede. (Imughan 4:8, 11) Jihova nọkan ree nẹ iṣẹbalẹ, kẹnrẹn o wa winọrọn gbegberegbe.—Sam 90:2.
KỌ GBA MAN NI
Fẹnẹ gho ukanrin ti o wi ẹgbelemeeji akpuja Oriṣẹ biri ọrukọ ro ti aa ri egbe ro. Kẹnrẹnfọ, ẹnẹ wa kọ biri won te mu ọrukọ ro ghan uwọ, kẹnrẹn urun ti won teri ro ṣe wẹrẹ.
3. Oriṣẹ nẹ akpuja gidijẹ, dẹ ọrukọ ọkan
Gba ri ukanrin ti o wi akpuja oniye biri ọrukọ ro, lu VIDIO we, kuro di aghan fọ ni ubirọ ti o lele.
-
Nikọ re ṣe ukanrin ti o wi akpuja ṣiṣi “Ọluwa,” biri ọrukọ sin?
Baibol gin, gin irẹye ka sẹn oriṣẹ gidijẹ biri ọluwa gidijẹ. Rọ Diutaronomi 10:17, kuro di aghan fọ ni ubirọ we:
-
Oriṣẹ bokọ re nẹ nini ju ni ẹbu oriṣẹ ghaan dede?
4. Jihova fẹ di wo man ọrukọ ro, kẹnrẹn gba lo o
Bokọ wo te man gin Jihova fẹ di wo man ọrukọ ro? Lu VIDIO we, kuro di aghan fọ ni ubirọ ti o lele.
-
Nikọ wo gba ro gin Jihova fẹ di a man ọrukọ ro?
Jihova fẹ di irẹye lo ọrukọ ro. Baibol gin: “Oniye-ki-oniye ti o ma kpe ọrukọ Jihova re wa ye.” (Rom 10:13, nwt) Kuro di aghan fọ ni ubirọ ghaan:
-
Gba lo ọrukọ Oriṣẹ, ti o ṣe Jihova, bokọ o te wọrun to o?
-
Bokọ o te ka ṣe ẹ ni ara ni oniye ma tigbi ọrukọ rẹ, gba gba a gba kpe ẹ?
-
Bokọ wo ro gin o te ṣe Jihova, ni wo ma lo ọrukọ ro?
5. Jihova fẹ di wo ṣe olukun ro
Onobirẹn ọkan ti o ti Cambodia wa ti ọrukọ ro ṣe Soten ka gin, “Gba man ọrukọ Oriṣẹ lẹghẹ gbẹ ara gba yọn mi ju biri o te ka yọn mi ṣi.” Lu VIDIO we, kuro di aghan fọ ni ubirọ ti o lele.
-
Ni vidio we, bokọ o te ṣe Soten ni ara ti won gba man ọrukọ Oriṣẹ?
Di we si ba oniye mu ukun, wo wa ṣọgua man ọrukọ ro tẹnrẹn. Rọ Jemisi 4:8a, kuro di aghan fọ ni ubirọ ghaan:
-
Nikọ wun Jihova fẹ di wo ṣe?
-
Gba man ọrukọ Oriṣẹ kẹnrẹn gba lo o, bokọ o te wa tin ẹ ẹyin gba kpinmaa ni?
IRẸYE BỌBỌ GIN: “Wo nemi kpe Oriṣẹ ọrukọ-ki-ọrukọ.”
-
Wo kpe ni ọrọnfọ gin Jihova re ṣe ọrukọ Oriṣẹ?
-
Bokọ wo wa te wewe ro gin Oriṣẹ fẹ di ẹnẹ lo ọrukọ ro?
NIKỌ WO KỌ?
Jihova re ṣe ọrukọ Oriṣẹ ọkpọkpọrọkan ti o ṣe ọrọnfọ. O fẹ di ẹnẹ man ọrukọ we gba lo o, di ẹnẹ gba nemi kpinmaa ni.
Gba Fẹnẹ Gho
-
Bokọ Jihova te ṣe ukanrin kuri oriṣẹ mirẹn dede ti irẹye ka sẹẹn?
-
Nikọ o gba yẹle di ẹnẹ lo ọrukọ Oriṣẹ?
-
Nikọ re mughan gin Jihova fẹ di ẹnẹ biri o mu ukun?
FẸ ALẸ RO NI
Ko urun maaru ni uro ti o lẹghẹ ẹ da ẹnẹ eju gin Oriṣẹ winọrọn.
Nikọ o gba ṣe urun irẹ, gba kpe ni ọrọnfọ gin Oriṣẹ ee nẹ iṣẹbalẹ.
Kọ urun ti o lẹghẹ ẹ yẹle di a lo ọrukọ Oriṣẹ, o ma wu gin ẹnẹ ee man biri a te kpe e ni ira ẹghaarẹ.
Ẹnẹ nemi kpe Oriṣẹ ọrukọ-ki-ọrukọ? Ṣọn urun ti o lẹghẹ ẹnẹ teri ro nemi gin ọrukọ ọkan nọkan owun won nẹ.
a Wo ma fẹ man ni, ni ubara alẹ ọrukọ Oriṣẹ ọrọnfọ, biri urun ti o lẹghẹ Baibol bọbọ ti a yidẹ gba gba ọrukọ we kuri inọrọn, ṣọn Appendix A4 ni Baibol New World Translation of the Holy Scriptures. (Ni owun-aja Ighereje)