Re listi urun ti o winọrọn

Re listi urun ti o wi iwe we

ẸKỌ 39

Urun ti Oriṣẹ Gin Ni Ubara Isangi

Urun ti Oriṣẹ Gin Ni Ubara Isangi

Isangi, urun kpatakiri rẹẹn. Oniye ti ee nẹ isangi ni ara ee nemi wi ẹye. Oriṣẹ re da ẹnẹ, teri ẹrẹn owun re yẹle ọnẹ ti o wa gin gbẹ ẹnẹ biri ẹnẹ te wa lo isangi. Nikọ won gin ni ubara isangi? A nemi jẹ ẹ wẹrẹ gba kpe e ni ara? Kẹnrẹn bokọ wo te nemi da ero ti o jọ ni ọfọ isangi we?

1. Nikọ wun Jihova gin ni ubara isangi?

Jihova gin gbẹ aghan ọmẹnrẹn ro ni ira ẹghaarẹ gin: “Ẹmi urun-ki-urun ti o wi ẹye we re wi inọ isangi ro.” (Lẹfitikọs 17:14) Ni eju Jihova, isangi soro gbẹ ẹmi. Ẹmi, orire-ọfẹ kpatakiri ti o ti ẹwọ Oriṣẹ wa rẹẹn, wẹrẹ kẹnrẹn isangi gha.

2. Ewe biri a te lo isangi bokọ wun Oriṣẹ kọkọ?

Di a e si ṣẹ ujọ Olele Kraist, Jihova mu ẹsi ṣi gbẹ aghan ọmẹnrẹn ro gin di aghan maa jẹ isangi. (Rọ Jẹnẹsis 9:4 biri Lẹfitikọs 17:10.) Ti a gba ṣẹ ujọ Olele Kraist kuro, Jihova datu bari ẹsi we. Aghan ọbejuto uṣẹ ni ẹye dede ka gin gbẹ aghan Olele Kraist gin “aghan maa jẹ isangi [“kẹnẹ ara gbẹ isangi,” nwt].”—Rọ Uṣe 15:28, 29.

Nikọ won jẹ gba kẹnẹ ara gbẹ isangi? Ẹwo-oyibo ma gin di wo kẹnẹ ara gbẹ ẹmọn ti o ja, wee wa mọọn. Dẹreke, wo wa jẹ ọjẹ ti o nẹ ẹmọn ti o ja wẹrẹ gba forijẹ di a kpe e ni uwọ ara? O ye ẹnẹ gin wee wa jẹ. Ni ewe ọkan we, ẹsi Oriṣẹ gin di ẹnẹ kẹnẹ ara gbẹ isangi ka jẹ gin, ẹnẹ ee wa jẹ wẹrẹ gba mọn isangi, wẹrẹ kẹnrẹn ẹnẹ ee wa jẹ ẹran oko ti aa bu wun ugunrọn gbẹ isangi ro gba guọ lẹfun. Dadagin gba jẹ ọjẹ ti a gba isangi gba se.

Ẹwo-oyibo nemi fẹ lo isangi gba dun oniye. Ni ewe, aghan nemi fẹ kpe isangi kitikiti ni ara oniye, wẹrẹ ọkan ni ẹbu ẹkoko urun mẹẹrẹn ti o wi isangi: red cell, white cell, platelet, wẹrẹ plasma. O ṣe kpetekpete gin ewe ghaan ti a kele lo isangi ba ẹsi Oriṣẹ jẹ. Dẹreke dẹ, o nẹ ewe bọbọ mirẹn ti ẹwo-oyibo kele lo isangi, ti Baibol ee mu ẹsi ṣi ni ubara ro: Aghan nemi gba urun tie tie bọbọ kuri isangi, ṣiṣi protein, vitamin, wẹrẹ urun mirẹn kuri red cell, white cell, platelet wẹrẹ plasma ti aghan wa lo gba ṣe irawọ bọbọ. Ni ewe mirẹn ti a kele dun oniye, ẹwo-oyibo nemi fẹ lo isangi ọnẹ ti a winọrọn dun we. Wo man winọrọn ro ni ubara ewe mirẹn ghaan ti a kele dun irẹye, man gin ikẹnẹkun lati da ero urun ti won wa ṣe gbẹ ara ro. aGaleṣia 6:5.

KỌ GBA MAN NI

Fẹnẹ biri wo wa te da ero ewe biri a te dun ara ti wo wa forijẹ ni gho.

3. Da ero ewe biri a te dun ara ti o wa wu Jihova

Bokọ wo wa te da ero ewe biri a dun ara ti a kele lo isangi ti o wa biri ẹsi Oriṣẹ kpa? Lu VIDIO we, kuro di aghan fọ ni ubirọ we. Nikọ o gba wọrun di wo gbe uta-ẹsẹn ghaan di uwọ e si da ero-ki-ero?

  • Bẹ Oriṣẹ gbẹ ọgban.—Jemisi 1:5.

  • Fẹnẹ ọrọnfọ ti o wi ẹyin ẹsi Baibol bọbọ gho gba man ti wo wa nemi lo.—Owe 13:16.

  • Fẹ alẹ ewe bọbọ ti a ka lo gba dun ara ni ubo ti wo gha.

  • Man ewe ti a kele dun ara ti wee wa forijẹ ro.

  • Ri gin wo da ero ti ẹmi rẹ ee kele wa da ẹbi gbẹ rẹ.—Uṣe 24:16. b

  • Di o ye ẹ gin ni ero ti o yẹle di wo gba ẹmi rẹ da, ee ṣe oniye-ki-oniye, o ma wu di o ṣe ọkọ wẹrẹ aya rẹ, ẹghaarẹ ni ujọ, wẹrẹ ọnẹ ti o winọrọn biri uwọ kọ ẹkọ Baibol, re wa gin urun ti wo wa ṣe gbẹ rẹ.—Rom 14:12.

  • Ya urun ti wo da ero ro ṣi alẹ.

4. Oṣẹri Jihova ka fẹ ewe ti a kele dun ara ti o san ju fẹnẹfẹnẹ

A nemi da ẹsi Oriṣẹ ni ubara isangi ni, gba kpe dun ara ni ewe ti o san ju ni are-maa lo isangi. Lu VIDIO we.

Rọ Taitọs 3:2, kuro di aghan fọ ni ubirọ we:

  • Nikọ o gba yẹle di ẹnẹ gba ọghọ biri ẹdọn kpẹtẹkpẹtẹ gba biri ẹwo-oyibo fọ?

Ti aa forijẹ ro

Ti Olele Kraist wa da ero ro

A. Blood plasma.

Urun tie tie ti a gba kuri plasma

B. White cell.

Urun tie tie ti a gba kuri white cell

C. Platelet.

Urun tie tie ti a gba kuri platelet

D. Red cell.

Urun tie tie ti a gba kuri red cell

 5. O ma ṣe urun tie tie ti a kpe nemi gba kuri isangi

O nẹ ẹkoko urun mẹẹrẹn ti o wi isangi—red cell, white cell, platelet, biri plasma. Ẹkoko urun mẹẹrẹn ghaan kpe nẹ urun tie tie gidijẹ ni inọrọn, ti a kpe urun tie tie ni isangi. c A ka lo urun tie tie ghaan gba ṣe irawọ ti o ka kighi ara we kuri ikobo, wẹrẹ gba le isangi ti o winọrọn guọ sin.

Ni ubara urun tie tie ti a gba kuri isangi, Olele Kraist ọkan-ọkan lati gba ẹmi ro ti won gba Baibol kọ gba da ero gbẹ ara ro. Aghan bọbọ nemi da ero gin aghan ee wa forijẹ ni ewe bọbọ biri a te dun oniye ti a kele lo urun tie tie ghaan ti a gba kuri isangi. Gbẹ aghan bọbọ dẹ, ẹmi aghan nemi forijẹ ni lilo urun tie tie ghaan ti a gba kuri isangi.

Wo ma winọrọn da ero rẹ, ko ubirọ ghaan ni uro:

  • Nikọ mo wa teri ro forijẹ wẹrẹ gba kọkọ lilo urun tie tie ghaan bọbọ ti a gba kuri isangi? Bokọ mo wa te wewe eyiwe gbẹ ẹwo-oyibo?

IRẸYE BỌBỌ GIN: “Mee man urun ti o buru ni isangi ti a kpe ni ara oniye—o ka gbe ẹmi irẹye.”

  • Nikọ re wa ṣe iwanran rẹ?

NIKỌ WO KỌ?

Jihova ee fẹ di ẹnẹ lo isangi eju-oghori.

Gba Fẹnẹ Gho

  • Nikọ isangi gba ṣe urun ti o wi oriọghan ni eju Jihova?

  • Bokọ ẹnẹ te man gin ẹsi Oriṣẹ gin di ẹnẹ kẹnẹ ara gbẹ isangi kpe kan isangi ti a kpe ni oniye ara kẹnrẹn?

  • Bokọ wo wa te nemi da ero ti o jọ ni ubara ewe biri a te dun oniye ti a kele lo isangi?

Dan Eyi Gho

FẸ ALẸ RO NI

Nikọ wo wa ko ni uro tẹnrẹn di uwọ e si forijẹ ni ewe biri a te dun oniye ti a kele wa lo isangi rẹ kawọ?

“Ubirọ ti Aghan Ti O Ka Rọ Iwe Ẹnẹ Ka Birọ” (The Watchtower, October 15, 2000)

Nikọ wo wa ko ni uro tẹnrẹn di uwọ e si forijẹ ni lilo urun tie tie ghaan ti a gba kuri isangi?

“Ubirọ ti Aghan Ti O Ka Rọ Iwe Ẹnẹ Ka Birọ” (The Watchtower, June 15, 2004)

Nikọ re lẹghẹ ẹwo-oyibo ọkan gin irẹ wi eju ti Jihova gba ṣọn isangi?

“Eju ti Jihova Gba Ṣọn Isangi Owun Mo Forijẹ Ni” (Awake!, December 8, 2003)

Kọ biri aghan ẹghaarẹ ti o winọrọn biri Kọmiti Ọnẹ-Ẹgbelemeeji Ọlọkunrọn Biri Ẹwo-Oyibo ṣe uṣẹ te mu utiẹyin gbẹ aghan omere ẹkẹnrẹn biri ebirẹn.

Jihova Ka Ṣe Ọnutiẹyin gbẹ Aghan ti Ubo Dọn (10:23)

a Ṣọn Ẹkọ 35, “Bokọ Ẹnẹ A Te Da Ero ti O Jọ?”

b Ṣọn  ẹkori 5, “O Ma Ṣe Urun Tie Tie ti A Kpe Nemi Gba Kuri Isangi;” biri Ọfọ ti O Wi Ogun Iwe We 3, “Ewe Aradidun ti A Kele Lo Isangi.”

c Ẹwo-oyibo ghaan bọbọ ka kpe ṣọn ẹkoko urun mẹẹrẹn ghaan ṣiṣi urun tie tie ti a gba kuri isangi. Teri ẹrẹn, ri gin ẹwo-oyibo rẹ nẹ oye ero ti wo nọkan da, gin di a maa kpe isangi kitikiti wẹrẹ red cell, white cell, platelet, tabi plasma ni ara rẹ.