Re listi urun ti o winọrọn

Re listi urun ti o wi iwe we

January 6-12

SAM 127-134

January 6-12

Ẹrin 134 Biri Iṣẹ | Ọfọ Ọṣọgua ti Ọlaga Wa Fọ (uṣẹju 1)

UWA TI O TI ỌFỌ ORIṢẸ WA

1. Aghan Ọsa Biri Ore, Aghan Ka Jọlọ Bejuto Orire ti O Jọlọ Ghan ti Jihova Mu gbẹ Aghan

(uṣẹju 10)

Aghan ọsa biri ore, di o da aghan eju gin Jihova wa mu utiẹyin gbẹ aghan gba nemi bejuto ẹbi aghan (Sam 127:​1, 2)

Orire ti o jọlọ ghan ti o ti ẹwọ Jihova wa owun ọma ṣe (Sam 127:3; w21.08-E 5 ¶9)

Ọma dede ee ṣe ọkan, teri ẹrẹn kọ aghan ọkan-ọkan ni ewe ti aghan wa gba nẹ oye ẹkọ we (Sam 127:4; w19.12-E 27 ¶20)

Jihova ka fẹ ọfọ ro ni aghan ọsa biri ore ma gbiyẹle e, biri gba ṣe urun ti ẹmi aghan ka gba bejuto ọtọn aghan

2. Uwa Ẹmi

(uṣẹju 10)

  • Sam 128:3—Nikọ re ṣe ti ọyiwe sam we gba wewe ọtọn oniye ṣiṣi egin olif wẹrẹ ita egin olif? (it-1-E 543)

  • Uwa ẹmi bokọ wo ri ni Baibol ti a rọ ni ọjijala eyiwe ti wo wa fẹ fọ ni ubara ro?

3. Rirọ Baibol Usoro

(uṣẹju 4) Sam 132:​1-18 (th ẹkọ 2)

KA WOWO ỌFỌ WE NI ODE

4. Mimu Arun ni Ọfọ

(uṣẹju 3) IRA TI ỌFỌ MA ṢI ỌFỌ. (lmd ẹkọ 1 ẹkori 3)

5. Mimu Arun ni Ọfọ

(uṣẹju 4) IRA TI ỌFỌ MA ṢI ỌFỌ. Ọnẹ gin urun ọkan ti won kpe ni ọrọnfọ, dẹ ee biri ẹkọ ti o wi Baibol kpa. (lmd ẹkọ 5 ẹkori 4)

6. Sisọ Irẹye Da Olele Kraist

(uṣẹju 5) lff ẹkọ 16 ẹkori 4-5. Wee wa wi aja gbẹ ira bọbọ. Biri ọma ẹkọ Baibol rẹ fọ ni ubara ijọlọṣi ti wo ṣe di o gba kpe kọ ẹkọ Baibol. (lmd ẹkọ 10 ẹkori 4)

KA DO UDOẸYE OLELE KRAIST

Ẹrin 13

7. Aghan Ọsa Biri Ore—Aghan Winọrọn Lo Ewe Aghan gba Kọ Ọtọn Aghan?

(uṣẹju 15) Ọfọ ti a fọ ni ara.

Ugbarajọ Jihova nẹ ṣe urun ẹkọ gidijẹ ti o wa mu utiẹyin gbẹ ọsa biri ore gba kọ ọtọn aghan ni ubara Jihova rẹn. Dẹ, ewe ọkan ti o san ju ti aghan ọsa biri ore gba nemi kọ ọtọn aghan ka ṣe ni aghan ma mu ọrọnrọn ewe ṣi gbẹ aghan.—Diut 6:​5-9.

Jisọs kẹnrẹn lo ewe eyiwe gba kọ aghan olele ro.

Rọ Jọn 13:​13-15. Kuro bi aghan ti o wi iṣikalẹ rọ:

  • Nikọ wo ro gin o lẹghẹ ewe ti Jisọs lo gba kọ aghan olele ro gba jọlọ san?

Wo ma ṣe ọsa wẹrẹ ore, uṣe rẹ nemi lẹghẹ ọtọn rẹ gba jọlọ nẹ oye urun ti wo kọ aghan. Wo ma mu ọrọnrọn ewe ṣi gbẹ aghan ọtọn rẹ, o wa ya gbẹ aghan gba rentin uwọ biri gba lele ẹkọ rẹ.

Lu VIDIO we Lilo Ewe Ẹnẹ gba Kọ Ọtọn Ẹnẹ. Kuro bi aghan ti o wi iṣikalẹ rọ:

  • Ẹkọ kpatakiri bokọ omere ọnọkẹnrẹn biri onobirẹn Garcia kọ ọtọn aghan ebirẹn?

  • Vidio we lẹghẹ uwọ gba fẹ ka mu ọrọnrọn ewe ṣi gbẹ aghan ọtọn rẹ? Teri nikọ?

8. Ẹkọ Baibol ti Ujọ Dede

(uṣẹju 30) bt origho 20 ¶13-20

Ọfọ ti A Wa Gba Gba Ẹkọ We To Ogun (uṣẹju 3) | Ẹrin 73 Biri Iṣẹ