July 8-14
SAM 60-62
Ẹrin 2 Biri Iṣẹ | Ọfọ Ọṣọgua ti Ọlaga Wa Fọ (uṣẹju 1)
1. Jihova Ka Bejuto Ẹnẹ, O Ka Kighi Ẹnẹ, Kẹnrẹn Ẹnẹ Nemi Gbiyẹle E
(uṣẹju 10)
Jihova gha ṣiṣi ubo ikirimọn (Sam 61:3; it-2-E 1118 ¶7)
Jihova gba ẹnẹ wọ uli-afiala ro (Sam 61:4; it-2-E 1084 ¶8)
Ẹnẹ nemi gbiyẹle Jihova kẹnrẹn ee ka yidẹ (Sam 62:2; Mal 3:6; w02-E 4/15 16 ¶14)
BI ARA RẸ RỌ, ‘Bokọ ẹye mi te san ni rẹn biri-ọjọ-ghawe ti mo gba man Jihova, biri ti mo gba gbiyẹle e?’
2. Uwa Ẹmi
(uṣẹju 10)
Sam 62:11—Nikọ won jẹ gba gin ‘nini dede wi ẹwọ Oriṣẹ’? (w06-E 6/1 11 ¶6)
Uwa ẹmi bokọ wo ri ni Baibol ti a rọ ni ọjijala eyiwe ti wo wa fẹ fọ ni ubara ro?
3. Rirọ Baibol Usoro
(uṣẹju 4) Sam 60:1–61:8 (th ẹkọ 10)
4. Mimu Arun ni Ọfọ
(uṣẹju 3) IRA TI ỌFỌ MA ṢI ỌFỌ. Ṣẹ fifọ ni ara biri ọnẹ ti o ṣe urun ti o san gbẹ rẹ. (lmd ẹkọ 2 ẹkori 3)
5. Liludẹ Buru
(uṣẹju 4) KURI ẸGẸRIFO RA WỌ ẸGẸRIFO. Gin gbẹ ọluli we ni ubara JW Library® appu we, kẹnrẹn wewe biri won wa te nẹ ni fonu ro gbẹ ẹ. (lmd ẹkọ 7 ẹkori 4)
6. Ọfọ
(uṣẹju 5) w22.02-E 4-5 ¶7-10—Origho Ọfọ: Gbiyẹle Jihova Ni Ugbarajọ Ro Ma Gin Urun ti Wo Wa Ṣe Gbẹ Rẹ. (th ẹkọ 20)
Ẹrin 12
7. Urun-Ki-Urun Ee “Nemi Wana Ẹnẹ Kuri Wuwu Oriṣẹ”
(uṣẹju 10) Ọfọ ti a fọ ni ara.
Lu VIDIO we. Kuro bi aghan ti o wi iṣikalẹ rọ:
Ewe bọbọ bokọ owun Jihova te bejuto Omere ọnọkẹnrẹn Nyirenda ti won gba jẹ uya teri ukpeọrọnfọ ro?
8. Biri Jihova Ṣe Ukun—Uta-Ẹsẹn ti A Ka Gbe Di A E Si Gba-Omi
(uṣẹju 5) Ọfọ ti a fọ ni ara. Lu VIDIO we. Kuro, o ma ṣe-ayẹ, kpe ọma bọbọ ti wo fẹsẹn ṣi wa ni ẹkete we gba bi aghan rọ: Oniye ma fẹ gba-omi, nikọ re ṣe kpatakiri ju olu ọdọn ti ọnẹ ṣe? Nikọ re ṣe uta-ẹsẹn bọbọ ti oniye wa gbe di o gba nemi gba-omi?
9. Ẹkọ Baibol ti Ujọ Dede
(uṣẹju 30) bt origho 12 ¶7-13, ẹkpetin ti o wi peji 97