Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì

Ìkìlọ̀ tí Jésù fún wa ni nǹkan bí ẹgbàá [2,000] ọdún sẹ́yìn ti wá ṣe pàtàkì gan-an lásìkò yìí ju ti ìgbàkígbà rí lọ. Nínú fídíò yìí, ẹ máa rí bí Brian àti Gloria ṣe kọ́ bí wọ́n á ṣe dáàbò bo ìdílé wọn lọ́wọ́ ewu tí Jésù kìlọ̀ nípa rẹ̀ yìí.

Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì—Apá Kìíní

Báwo ni ìdílé Kristẹni kan lóde òní ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyè méjì nípa ìdúrọ́ṣinṣin wọn sí Ọlọ́run àti lílépa ọrọ̀?

Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì​—Apá Kejì

Kí ló lè dí wa lójú nípa tẹ̀mí, kó sì mú ká bẹ̀rẹ̀ sí í fara mọ́ èrò ayé lórí àwọn ọ̀rọ̀ kan?

Ẹ Rántí Aya Lọ́ọ̀tì​—Apá Kẹta

Jésù mẹ́nu ba ìtàn yẹn kó lè jẹ́ ẹ̀kọ́ fún wa. Kò yẹ kó jẹ́ ibi tó máa parí ayé ẹ̀ sí nìyẹn, kó sì yẹ kóhun tó ṣẹlẹ̀ sí aya Lọ́ọ̀tì ṣẹlẹ̀ sí wa.