Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá

Gbọ́ ohun tí oríṣiríṣi àwọn èèyàn sọ pé ó mú káwọn gbà pé Ẹnì kan ló dá gbogbo nǹkan.

Monica Richardson: Dókítà Kan Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Obìnrin yìí rò ó bóyá ẹnì kan tó gbọ́n ló ṣètò ọmọ bíbí lọ́nà àrà àbí ó kàn ṣèèṣì rí bẹ́ẹ̀. Kí lohun tó ti mọ̀ nídìí iṣẹ́ dókítà tó ń ṣe mú kó parí èrò sí?

Massimo Tistarelli: Ẹni Tó Ń Ṣe Rọ́bọ́ọ̀tì Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ó gbà pé ohun tí sáyẹ́ǹsì bá sọ labẹ́ gé, àmọ́ ó bẹ̀rẹ̀ sí í tún èrò ẹ̀ pa lórí ọ̀rọ̀ ẹfolúṣọ̀n.

Petr Muzny: Ọ̀jọ̀gbọ́n Nípa Òfin Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Ìgbà tí àwọn Kọ́múníìsì ń ṣèjọba ni wọ́n bí Petr. Wọ́n gbà pé ẹni tórí ẹ̀ ò pé ló máa sọ pé Ẹlẹ́dàá wà. Wo bó ṣe yí èrò ẹ̀ pa dà.

Irène Hof Laurenceau: Dókítà Tó Ń To Egungun Ṣàlàyé Ohun Tó Gbà Gbọ́

Iṣẹ́ eegun títò tó ń ṣe mú kó tún inú rò lórí ohun tó gbà gbọ́.

O Tún Lè Wo

ÌMỌ̀ SÁYẸ́ǸSÌ ÀTI BÍBÉLÌ

Èrò Àwọn Èèyàn Nípa Ìṣẹ̀dá

Àwọn onímọ̀ nípa ohun alààyè, àwọn onímọ̀ nípa ìṣesí àwọn ohun abẹ̀mí, àwọn dókítà, àwọn oníṣẹ́ abẹ àtàwọn míì sọ̀rọ̀ lórí bí ìwàláàyè ṣe bẹ̀rẹ̀ lẹ́yìn tí wọ́n fi àwọn ìwádìí tí wọ́n ṣe wé ohun tí Bíbélì.